You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ifeanyichukwu Chiejine: Agbábọ́ọ̀lù Chiejine jáde láyé lẹ́yìn ààsàn ráńpẹ́
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1
Iku doro, iku ṣeka, agbabọọlu Super Falcons Naijiria tẹlẹ ri, Ifeanyichukwu Chiejine ti jade laye lẹni ọdun mẹrindinlogoji.
Ajọ to n ri si ere bọọlu ni Naijiria lo kede iku Chiejine loju opo Twitter wọn lọsan Ọjọbọ.
NFF ṣalaye loju opo wọn pe agbabọọlu Naijiria tẹlẹ ri naa ku lẹyin aisan ranpẹ.
- Buhari gbóṣùbà fún D'Tigress lẹ́yìn tí wọ́n lu Senegal gba ife AfroBasketWomen
- Manchester United dáná sun Chelsea bi ẹràn àgbò iléyá
- PFN: Fatoyinbo kọ̀ láti yọjú ni ìwádìí wa kò ṣe parí
- Àjẹ́ àti Aṣẹ́wó ní ìyá Rainbow - Òjòpagogo
- Ọlọ́pàá Germany ń wádìí àfurasí mẹ́rin nínú àwọn tó kọlu Ekweremadu ni Germany
Chiejine ṣoju Naijiria nigba mọkanlelọgọta, bẹẹ lo si gba goolu mẹẹdogun sawọn nigba aye rẹ.
Chiejine ni balogun ẹgbẹ agbabọọlu obinrin Naijiria akọkọ tọjọ ori wọn ko ju ọdun mọkandinlogun lọ ninu idije ife ẹyẹ agbaye lọdun 2002.
NFF ṣalaye pe Ọjọru ọsẹ yii ni agbabọọlu naa dagbere faye.