FIFA: A fi òfin de ẹ̀yin eléré ìdárayá mẹ́ta wọ̀nyí láti ilẹ̀ Adúláwọ̀ títí ayé

Bi ko ba nidi, ẹ̀ṣẹ́ kìí déédé ṣẹ́ ni àwọn agba maa n wi nilẹ̀ Oodua.

Lọjọ kẹrindinlogun, oṣu kẹjọ, ọdun yii ni ajọ to n mojuto ọrọ ere bọọlu ni agbaye FIFA fi ofin de SiasiaSiasia ń gbèrò àti gbé FIFA lọ sí ilé ẹjọ́ .

Samson Siasia jẹ agbabọọlu to pegede fun Naijiria ni ọpọlọpọ ọdun ko too di akọnimọọgbaÀjọ Fifa fòfin de Samson Siasia títí láíláí .

Ofin ayeraye ni ajọ FIFA fi de akọnimọọgba SIasia ti iya rẹ ṣi wa ni akata awọn ajinigbe bayii.

Ẹsun ti igbimọ tẹẹkoto to n risi iwa ibajẹ fun ajọ FIFA fi kan Siasia ni ẹsun riba.

Wọn ni o fi ifẹ han lati gba riba ki ẹgbẹ agbabọọlu rẹ le gba bọọlu bi o ti wu wọn ninu idije ni eyi to lodi si ofin FIFA.

Lọdun 2010 si ọdun 2011 ni Siasia fi ṣe akọnimọọgba fun ikọ agbabọọlu ti wọn ko kọja ogun ọdun si ọdun mẹtalelogun lọ.

Iroyin ni ọjọ kọkanla, oṣu keji ọdun 2019 ni FIFA ṣe iwadii rẹ lori ọrọ Wilson Raj Perumal pe wọn ṣe magomago ninu idije.

FIFA fofin de Siasia pe ko gbọdọ ni nkankan ṣe pẹlu ere idaraya bọọlu alafẹsẹgba mọ titi aye.

Wo àwọn elére ìdárayá míran ti FIFA ti fòfin ayérayé dè:

Kwesi Nyantakyi:

Kwesi jẹ ọkan gboogi lara awọn to ni i ṣe pẹlu ọrọ bọọlu alafẹsẹgba ni ilẹ AdulawọÀwọn ọlọ́pàá ọtẹlemuye gbé Nyantakyi .

FIFA fi ofin ayeraye dee pe o gba riba ni eyi ti wọn fi yọọ nipo.

Koda iṣẹlẹ ọrọ riba yii ni Kwesi ba kuro nipo gẹgẹ bii aarẹ ajọ to n mojuto ọrọ ere bọọlu ni Ghana.

Ibrahim Kargo:

Elomii ti ajọ FIFA tun ti fofin ayeraye de ninu awọn ọmọ Adulawọ ni Ibrahim Kargo.

Agbabọọlu Sierra Leone to tun je balogun ẹgbẹ rẹ ni wọn ni o ṣe magomago.

Ṣugbọn ajọ FIFA ko sọ ni pato ohun to ṣe ati idije to da bi ọgbọn si.

Mooketsi Kgotlele:

Ọjọ kejilelogun, oṣu keje ni ajọ FIFA fofin de ọmọ orilẹ-ede Botswana yii.

Kgotlele ni akọwe agba fun ajọ to n mojuto ọrọ ere bọọlu ni Botswana (BFA).