You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Siasia lè gba iṣẹ́ akọ́nimọ̀ọ́gbá égbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Cameroon
Akọ́nimọ̀ọ́gbá ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù Super Eagles tẹ́lẹ̀ rí, Samson Siasia, wà lára àwọn akọ́nimọ̀ọ́gbá mẹ́tàdínlọ́gọ́rin tí àjọ tó ń rí sí eré bọ́ọ̀lù àfẹsẹ̀gbá ní orílẹ́èdè Cameroon fẹ́ fọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò láti tukọ̀ ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù ilẹ̀ náà.
Àjọ tó ń rí sí eré bọ́ọ̀lù àfẹsẹ̀gbá ní Cameroon ń wá ẹni tí yóò rọ́pò Hugo Broos látàrí bí orílẹ́-èdè náà ti kùnà láti yege nínú àwọn tí yóò kópa nínú ife ẹ̀yẹ àgbáyé ọdún yìí ní orílẹ́-èdè Russia.
Àwọn míràn tí wọ́n tún yàn fún àyẹ̀wò fún isẹ̀ náà ni: Balógun ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù Cameroon tẹ́lẹ̀rí, Rigobert Song; akọ́nimọ̀ọ́gbá ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù Super Eagles nígbàkan rí, Philippe Troussier; àti akọ́nimọ̀ọ́gbá égbẹ́ agbábọ́ọ̀lù ilẹ̀ Faransé tẹ́lẹ̀ rí, Raymond Domenech.
Olórí ìgbìmọ̀ tó ń rí sí yíyan akọ́nimọ̀ọ́gbá míràn fún orílẹ́-èdè Cameroon, Djomo Kelvin, sọ pé àwọn yóò se àyẹ̀wò fínífíní kí awọ́n tó yan akọ́nimọ̀ọ́gbá tuntun fun égbẹ́ agbábọ́ọ̀lù ọ̀hún.