You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Premier League: Ta ni yóò gba Premier League láàrin Man City àti Liverpool?
Oni lonii jẹ ẹni a bẹ lọwẹ! Loni ọjọ kejila, oṣu karun un ni idije Premier League yoo wa s'ipari ti a o si mọ ikọ agbabọọlu ti yoo gba ife ẹyẹ naa laarin Manchester City ati Liverpool.
Liverpool fẹ gbiyanju lati di ikọ agbabọọlu keji ninu itan ti yoo gba ife ẹyẹ Premier League mọ ikọ to n siwaju lọwọ lọjọ ti idije naa pari.
Liverpool to n tele Manchester City pẹlu ami ayo kan yoo gbalejo Wolves ni papa iṣẹre Anfield nigba ti Man City yoo waako pẹlu Brighton ni deedee aago mẹta ọsan ọjọ Aiku.
- Beckham, àgbábọ́ọ́lù tẹ́lẹ̀ rèé tó ń sọ èdè Yorùbá
- Sàǹgbá fọ́! Liverpool fí ogun ẹ̀yìn ja Barcelona
- Ẹni a le mú...Chelsea dìgbájú ru Watford bí olè tó jí ike owó
- Olódo méjì! Arsenal àti Manchester United kọ́wọ̀ọ́ rìn lọ Europa
- Champions League: Ajax f'imú Tottenham fọn fèrè
- Ìyá 73 rọ ọmọ ní oúnjẹ dèrò ẹ̀wọ̀n l'Ámẹ́ríkà
Man City ti gbayo mọkanlelaadọrun un sawọn ninu ifẹsẹwọnsẹ mẹtadinlogoji ti wọn ti gba ni saa yii nigba ti Liverpool gba goolu mejidindinlaadọrun sawọn.
Bakan naa, awọn mejeeji sun mọ ara wọn pẹkipẹki lori tabili Premier League lẹyin tu Man City n fi ami ayo marun le laadọrun siwaju ti Liverpool si wa ni ipo keji pẹlu ami ayo mẹrinlelaadọrun.
Igba kẹjọ re e ti idije ti ikọ to gba Premier League yoo foju han lọjọ ti idije naa pari.
Liverpool to ti pegede fun aṣekagba idije UEFA Champions League ko tii ri ife ẹyẹ Premier League fun ọgun mọkakandinlọgbọn bayii.
Ẹwẹ, akọnimọọgba Man City, Pep Guardiola ti sọ pe gbagbagba bii ike lawọn alatilẹyin City yoo ṣe gbaruku ti wọn nigba ti wọn ba koju Brighton.
Bakan naa, ẹgbẹ agbabọọlu Liverpool sọrọ loju opo Twitter pe, ikọ naa ti gbiyanju ni saa ohun kohun to wu ko ṣẹlẹ lonii
Man City yoo di ikọ agbabọọlu akọkọ ti yoo gba ife ẹyẹ Premier League lera wọn laarin ọdun mẹwaa sẹyin ti wọn ba gba ife naa mọ Liverpool lọwọ lonii.