You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ajax k'ógun ja Tottenham, àlù mọ́lé ni wọ́n nà wọ́n
Ẹkọ ko ṣ'oju mumu fun ikọ agbábọ́ọ̀lù Tottenham, bi ikọ agbabọọlu Ajax ṣe fi ìya jẹ wọn mọle pẹlu ami ayo 0-1.
Ni ko pẹ ti ifẹsẹwọnsẹ ọhun tó n waye ni London bẹrẹ ni ọkan gboogi lara agbabọọlu Tottnham Jan Vertonghen, fara pa tí imu rẹ si n da ẹjẹ sorosoro.
Donny Van de Beek lo gba bọọlu sawọn Tottenham , ti bogbo igbiyanju ikọ Tottenham lati da a pada si ja si pabo.
Nigba ti abala keji ifẹsẹwọnsẹ naa bẹrẹ ni pẹrẹu, o dabi wi pe awọn ọmọ agbabọọlu Tottenham ti n jawe sobi, sugbọn gbogbo laalaa wọn ko yọri si rere.
Dele Ali tilẹ gbiyanju ko gba bọọlu sawọn Ajax , sugbọn pabo lo ja si.
Ẹ ma gbagbe pe ọdun 1996 ni ikọ Ajax ti de ipele ipari ninu idije Champions Legaue kẹyin , ti ikọ agbábọ́ọ̀lù Tottenham ko ti ẹ tii de'bẹ ri n inu itan wọn .