You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Zainab Habib:Zainab Habib tí ilẹ̀ Saudi Arabia pa irọ́ mọ́ pé o gbé cocaine tí gba sabuké NYSC!
Zainab Habib Aliyu ti ijọba orilẹede Saudi Arabia fi ẹsun kan pe o gbe oogun oloro ni ọjọ kini ana ti pari agunbanirọ rẹ.
Loṣu Kejila, ọdun 2018 ni awọn alaṣẹ ni orilẹede Saudi Arabia mu Zainab lasiko to lọ kopa ninu ijọsin Umrah pe o gbe oogun oloro.
Ọdun 2019 ni ijọba Naijiria kede pe arabinrin naa ti gba ominira, ti o si pada walẹ si Naijiria.
- Mo ti pinnu láti túṣu dé ìsàlẹ̀ ìkòkò lóríì ìdí tí kò sí ìdàgbàsókè ní Niger Delta - Buhari
- Ènìyàn 156 ló tún ṣẹ̀ṣẹ̀ lùgbàdì ààrùn Coronavirus ní ìpínlẹ̀ Eko
- A fura pé ejò lọ́wọ́ nínú ikú Tolu Arotile, ẹ ṣe ìwádìí ikú rẹ̀ - Afenifere, Gani Adams, Huriwa
- Ohun tí o kò mọ̀ nípa Ebila "One Million Boys" àti Ekugbemi, olórí ẹgbẹ́ òkùnkùn méjì tó da ìlú Ibadan rú
Adari ileeṣẹ to n risi ọrọ awọn ọmọ Naijiria to wa ni oke okun, Abike Dabiri-Erewa lo fi oju opo ikansiraẹni Twitter rẹ.
Abike Dabiri-Erewa gbadura wi pe ọna rẹ a dara.
Bi wọn ṣe fi ọmọbinrin naa sẹwọn, ni ijọba bẹẹrẹ iwadii to tu aṣiri pe awọn ikọ oloogun oloro kan lo maa n fi ọgbọn gbe oogun oloro sinu ẹrù awọn eniyan to n lọ si Saudi Arabia.
Aṣiri to tun ọhun lo mu ki wọn o yọju si ọọfisi orilẹede Saudi to wa ni ilu Abuja lati bẹrẹ igbesẹ lori bi Zainab yoo ṣe gba ominira.
Ìjọ̀ba Saudi ti tú Zainab tí wọ́n fẹ̀sùn òògùn olóró kàn sílẹ̀
Ijọba Naijiria ti kede pe wọn Zainab Habib Aliyu to wa ni ẹ̀wọ̀n l'orilẹede Saudi Arabia lori ẹsun gbigbe oogun oloro ti gba ominira.
Akọwe agba nileeṣẹ ijọba to wa fun ọ̀rọ̀ ilẹ okeere, Mustapha Suleiman lo kede iroyin naa sita nilu Abuja.
O ṣalaye pe nigba tijọba gbọ nipa bi wọn ṣe fi ọmọbinrin naa sẹwọn, ni ijọba bẹẹrẹ iwadii to tu aṣiri pe awọn ikọ oloogun oloro kan lo maa n fi ọgbọn gbe oogun oloro sinu ẹrù awọn eniyan to n lọ si Saudi Arabia.
Aṣiri to tun ọhun lo mu ki wọn o yọju si ọọfisi orilẹede Saudi to wa ni ilu Abuja lati bẹrẹ igbesẹ lori bi Zainab yoo ṣe gba ominria.
Awọn ẹ̀rí to wa nilẹ si lo mu ki awọn alaṣẹ Saudi tu ọmọbinrin naa silẹ.
O ni ọmọbinrin naa ti wa pẹlu awọn alaṣẹ ọọfisi orilẹede Naijiria to wa ni Saudi Arabia.
Baba ọmọbinrin naa, Alhaji Habibi Aliyu sọ fun BBC pe awọn oṣiṣẹ ijọba apapọ ti pe oun lori ẹrọ ibanisọrọ pe ọmọ oun ti gba ominira.
O ni botilẹjẹ wi pe oun ko ti i ba ọmọ oun sọrọ, ọkan oun balẹ bayii.
'Mo ṣẹṣẹ gba ipe naa tan ni, koda mi o le sọ bi inu mi ṣe dun to. Oni jẹ ọkan lara awọn ọjọ ti inu mi dun ju l'aye.
Bakan naa ni Alhaji Aliyu sọ pe nkan to ṣẹlẹ si ọmọ oun fihan pe ọpọ alaiṣẹ lo n jiya ẹsun ti wọn ko mọ nkankan nipa a rẹ.
Ẹwẹ, oluranlọwọ pataki fun aarẹ naa fi ikede itusilẹ rẹ sita loju opo Twitter rẹ.
Bakan naa, àwọn ọmọ Naijiria ti tú sí àwọn ojú òpó ayélujára láti bẹ̀rẹ̀ sí ni fi ọ̀pẹ́ fún ọlọ́run ti wọn si n gboriyin fun ijọba orilede Naijiria.