You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
AFCON 2019: Nàìjíríà wà ní ìsọ̀rí kan náà pẹ̀lú Burundi, Madagascar àti Guinea
Super Eagles yoo koju Burundi, Madagascar àti Guinea nínú ìdíje ife ẹ̀yẹ Afrika AFCON 2019.
Isọri mẹrin ni wọn pin awọn ikọ agbabọọlu ti yoo kopa ninu idije AFCON 2019 si.
Orilẹede Egypt ti o gbalejo idije naa wa ni isọri kinni pẹlu Zimbabwe, DR Congo ati Uganda.
Isọri kẹta ni Tanzania ti agbbọọlu Naijiria tẹlẹ Emmanuel Amuneke n dari wa pẹlu Kenya, Algeria ati Senegal.
Namibia, South Africa, Ivory Coast ati Morocco lo wa ni isọri kẹrin nigba ti Angola, Mauritania, Mali ati Tunisia wa ni isọri karun un.
Awọn ẹgbẹ agbabọọlu to wa ni isọri kẹfa Guinea Bissau, Benin, Ghana, ati Cameroon
Ẹwẹ, akọnimọọgba Super Eagles Gernot Rohr sọ pe oun fẹ lati gba ife ẹyẹ AFCON lọtẹ yii lẹyin to ti gbe Niger ati Gabon lọ si idije naa ri.