Man City vs Chelsea: Wọn ṣe ìyà fún Chelsea pẹ̀lú àmì ayo 6-0

Ẹgbẹ agbabọọlu Manchester city ti fi agba han ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea lẹyin ti wọn na wọn pẹlu ami ayo mẹfa si odo.

Sergio Aguero lo pegede julọ ninu ifẹsẹwọnsẹ to waye ni alẹ Ọjọ Àìkú.

Ẹgbẹ agbabọọlu Manchester City ọhun lo n leke tabili pẹlu ami ayo marunlelọgọta (65) lori atẹ tabili Premier League.

Liverpool naa pẹlu na Bournemouth, eleyii to ti mu ki ẹgbẹ agbabọọlu naa si wa ni ipo keji ni ori tabili.