EPL: Chelsea na Newcastle mọ́lé pẹ̀lú àmì ayò 2-1

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ikọ agbabọọlu Chelsea maa tun fakọyọ lẹyin ti wọn na ẹgbẹ agbabọọlu Newcastle mọle pẹlu ami ayo kan sodo ninu idije Premier League lọjọ Aiku.
Ẹlẹsẹ ayo Eden Hazard lo kọkọ gba bọọlu sawọn nigba ti ifẹsẹwọnsẹ naa de iṣẹju mẹrindinlọgọrin, ṣugbọn Joselu dayo naa pada lẹyin iṣẹju meje.
Ifẹsẹwọnsẹ naa le koko bi oju ẹja bi ikọ mejeeji ko ti fẹ gba fun ara wọn.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Ṣugbọn Chelsea jawe olubori lẹyin ti agbabọọlu Newcastle DeAndre Yedlin gbayo wọle ara rẹ eleyi to si mu ki Chelsea na wọn mọle.
Ikọ Chelsea ti jawe olubori ninu ifẹsẹwọnsẹ mẹta ti wọn ti gba bayii nnu idije Premier League fun saa yii.
Chelsea ti wa nipo keji bayii lori tabili idije Premier League nigbati Liverpool wa ni ipo akọkọkọ.
'Isẹ́ sì pọ̀ fún mi láti ṣe ní Liverpool'
Ẹwẹ, akọnimọọgba ẹgbẹ agbabọọlu Liverpool, Jurgen Klopp, ti ni isẹ si pọ fun oun lati ṣe ninu Idije Premier League.
Jurgen Klopp ni pe awọn agbabọọlu oun nilo lati se igbaradi to peye ki wọn ba le gbe igba oroke ni asekagba Idije Premier League ti saa yii.

Oríṣun àwòrán, Inpho
Liverpool lo wa ni oke tente tabili Premier League lẹyin ti wọn na ẹgbẹ agbabọọlu Brighton pẹlu ami ayo kan si odo.
Mohamed Salah to gba bọọlu wọ inu awọn nigba mejilelọgbọn ni saa to kọja, lo gba bọọlu wọle ni saa kinni idije ọhun ni papa isere Anfield.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Liverpool nikan ni ẹgbẹ agbabọọlu ti ko i ti i si ẹni to ṣì na wọn ni saa yii ninu Idije Premier League.
Liverpool pegede nitori Manchester City gba 1-1 pẹlu ẹgbẹ agbabọọlu Wolves ni opin ọsẹ.















