FIFA kò ní le f'òfin de Nàìjíríà lẹ́yìn tíjọba gba Amaju Pinnick ní Ààrẹ NFF

Amaju Pinnick

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Amaju Pinnick nàá tún ni ìgbákejì ààrẹ àjọ tó n mójútó bọ́ọ̀lù gbágbá ní ilẹ̀ Afrika, CAF
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Naijiria ti bọ lọwọ igbesẹ ti ajọ FIFA fẹ ẹ gbe lati f'ofin de bọọlu alafẹsẹgba l'orilẹede naa.

Eyi waye latari bi ijọba Naijiria ṣe ti sọ pe Amaju Pinnick ni oun da mọ ni Aarẹ ajọ to n mojuto bọlu gbigba ni Naijiria, NFF.

Saaju asiko yii ni FIFA ti fun Naijiria ni gbedeke di aago mejila ọsan ọjọ Aje, ogunjọ, oṣu Kẹjọ, 2018, lati yanju wahala to n koju ajọ NFF, lori taani yoo jẹ aarẹ ẹgbẹ. FIFA ti sọ tẹlẹ pe Amaju Pinnick ni oun damọ gẹgẹ bi aarẹ.

Ṣugbọn, o ku diẹ ki aago lu ni Laolu Akande, to jẹ Oluranlọwọ pataki fun igbakeji aarẹ, Yẹmi Ọṣinbajo, fi ikede kan sita lori Twitter pe, ijọba ti fi ipinnu rẹ ranṣẹ si ajọ FIFA.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

O ti pẹ diẹ ti wahala ti wa ninu ajọ NFF, lori ẹni to jẹ olori ajọ naa laarin Chris Giwa ati Amaju Pinnick.

L'ọsẹ to kọja, Giwa ati awọn alatilẹyin rẹ gba iṣakoso ọọfisi ajọ NFF to wa ni ilu Abuja, lẹyin ti ile ẹjọ kan to wa ni ilu Jos, fa igi le esi idibo to gbe Amaju Pinnick wọle gẹgẹ bi aarẹ.

Giwa gba iṣẹ́ lọwọ Mohammed Sanusi, to jẹ akọwe agba fun ajọ NFF, ati awọn ọmọ igbimọ oluṣakoso mi i.