World Cup: Àgbàọ̀jẹ̀ agbọ́ọ̀lú 10 tí kò gba ife ẹ̀yẹ àgbáyé rí

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Nibayii ti awọn agbaọje agbabọólu meji lagbaye Cristiano Ronaldo ati Lionel Messi ti dagbere fun idije ife ẹyẹ agbaye l'orilẹede Russia, ẹ jẹ ka wo awọn ìlúmọ̀ọ́ká agbọ́ọ̀lú 10 tí wọn kuna lati gba ife ẹ̀yẹ àgbáyé rí bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ènìyàn rí wọn bíì akọni.
1. Lionel Messi to jẹ balogun ikọ Argentina ni akọkọ.
Lionel Messi jẹ balogun ikọ Argentina ni akọkọ.
Messi to jẹ ọmọ ọdun mọkanlelegbọn le maa l'anfani miran láti kopa ninu idije ife ẹyẹ agbaye miran.
O wa lara ikọ agbabọọlu Argentina tó fidi rẹmi ninu aṣekagba idije ife ẹyẹ agbaye ọdun 2014 ni orilẹede Brazil.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
2. Cristiano Ronaldo
Ronaldo ti lọ si ife ẹyẹ agbaye lẹmẹrin ọtọọtọ ti ko si l'anfani lati gba ife ẹyẹ naa.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
3. Oliver Kahn
Oliver Kahn jẹ amule tẹlẹ ri fun orilẹede Germany ko gba ife ẹyẹ agbaye ri bo tilẹ je pe Germany ti gba ami ẹyẹ naa lẹmẹrin ọtọọtọ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
4. Paolo Maldini
Agbaọjẹ adi-ẹyin-mu Paolo Maldini ko ri ife ẹyẹ agbaye gba, bẹẹni orilẹede rẹ Italy gba ife ẹyẹ naa nigba mẹrin.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
5. Johann Cruyff
Gbajugbaja agbabọọlu fun Netherlands ni Johann Cruyff ṣugbọn o kuna lati gba ife ẹyẹ agbaye.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
6. Michel Platini
Michel Platini naa fakọyọ fun ilẹ Faranse nigbati o n gba bọọlu, ṣugbọn ko ri ife ẹyẹ agbaye gba fun orilẹede Faranse.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
7. Eusebio da Silva Ferreira
Eusebio ti fakọyọ ri ninu ife ẹyẹ agbaye nibi to ti gba ayo mẹsan wọle, ṣugbọn oun naa kuna lati gba ife ẹyẹ agbaye fun Portugal.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
8. Ferenc Puskas
Ferenc Puskas ni gbajugbaja agbabọọlu orilẹede Hungary to pegede julọ, ṣugbọn o wa lara awọn agbaọjẹ agbabọọlu ti ko gba ife ẹyẹ agbaye ri.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
9. Wayne Rooney
Rooney wa lara awọn ilumọọka ẹlẹsẹ ayo fun ilẹ Gẹẹsi, oun naa ko lanfani lati gba ife ẹyẹ agbaye.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
10. Raul Gonzalez
Raul to jẹ ẹlẹsẹ ayo to pegede fun orilẹede Spain nigbati o fi n gba bọọlu, amọ oun naa ko ri ife ẹyẹ agbaye gba.

Oríṣun àwòrán, Getty Images














