World Cup: France lu Argentina jáde pẹlú àmì ayò mẹ́rin

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Nínú ìfẹsẹwọnsẹ ẹlẹ́ni mẹrìndílógun tó ń lọ ní Russia, ní France ti lú Argentina pẹlú àmi àyo mẹrin sí mẹta, èyi to túmọ̀ sí pe Argentina ti pari ere ije tiwọn nínú ife ẹyẹ àgbáye ti ọdún yìí ní Russia
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Bótilẹ jẹ́ pé kí ìdíje too bẹrẹ gbogbo eniyan lo ti fojú si Lionel Messi lara gẹgẹ bi ẹni ti yóò gbe ogo Argentina ga, sùgbọn Mbappe ló ṣe ohun ìwúri mále gbagbe fún ikọ France.
Mbappe ló yí ìdíje pada lẹyin sáà akọkọ tí France fi jáwé olú bori, eyi ló ran Argentina kuro nibi ìdije ife ẹyẹ àgbéye tódún yìí lórílẹ̀-èdè Russia.








