You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Christiano Ronaldo: Agbábọ́ọ̀lù àràmọ̀ndà
Ọmọ agbábọ́ọ̀lù Portugal nnì, Christiano Ronaldo wọnú ìwé ìtan bí ó ṣe gbá ọ̀mì ayò mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ sínú àwọ̀n nínú ifẹsẹ̀wọnsẹ̀ orileẹ̀èdè rẹ̀ àkọkọ ní ọjọ́ Ẹtì nínú ìdíje ife ẹ̀yẹ̀ àgbáyé tó ń lọ lọ́wọ́ ni Russia.
Àwọn àwòrán tí ó ṣe àpèjúwe bí ó ṣe lọ rèé
Bí ifẹsẹ̀wọnsẹ̀ ṣe bẹ̀rẹ̀ ni wọ́n gbe e ṣubú tó sì jẹ góòlù wòmí-ngba a sí ọ....
...ọwọ́ ọ̀tún àwọn ni ó gba a sí
Ó dabí bí ẹni pé ọmọ ọdún mẹ́tàlélọ́gbọ̀n náà máa ń simi títí dìgbà tí ó máa dábírà ni.
Ní abala kejì ifẹsẹ̀wọnsẹ̀ náà ni ó tún gbá ọ̀mì ayò mìíran wọlé tó kọjá lẹ́gbẹ̀ẹ́ amúlé fún orileẹ̀èdè Spain, David De Gea.
Ronaldo kìí yé má fi orókún nu ilẹ̀ tó bá ti gbá ayò wọlé sí àwọ̀n.
Oríleẹ̀èdè alágbára méjì ló kọlu ara nínú ifẹsẹ̀wọnsẹ̀ náà. Ṣùgbọ́n kò sí ẹ̀tanú rárá láàrín Ronaldo àti Sergio Ramos. Ramos tilẹ̀ ràń lọ́wọ́ nígbà tó ṣubú.
Èyí tó jẹ́ àràmọ̀ndà jù nínú ayò mẹ́ta tó gbá wọlé ni èyí tó wáyé ní bíi ìparí ifẹsẹ̀wọnsẹ̀ náà.
Èyí ló fi sọ ayò ọjọ́ náà di ọ̀mì 3-3...
...ni Ronaldo bá bú ramúramù...
...ẹ mọ̀ pé kò le ṣàì má ṣán ọwọ́ bó ṣe máa ń ṣe.
Lẹ́yìn tí wọ́n fọn fèrè ìkẹyìn ni ó dì mọ́ amúlé Spain, De Gea.