You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Àmì ẹyẹ ọjọ ìbí 2018:Joshua pẹlú àwọn tí Ọbabìnrin Elizabeth dá lọ́lá
Gbajugbaja abẹṣẹ-ku- bi-ojo ọmọ bibi orilẹede Naijiria, tó n sójú ilẹ Gẹẹsi, Anthony Joshua ni Ọbabinrin Elizabeth ilẹ Gẹẹsi ti fun ni àmì ẹ̀yẹ OBE.
Wọ́n ṣe àyẹ́sí náà fun nítorí ipa ribiribi tó kó nínú ìdàgbàsókè èré ìdárayá ẹ̀ṣẹ kíkàn.
Joshua tó gba ìgbànú ẹ̀yẹ Olympic, tí ṣaájú gba àmì ẹ̀yẹ àpọ́nlé MBE ní ààfin Buckingham l'ọ́dún 2013.
Lọ́jọ́ Ẹtì ni Joshua tó ti gba bẹ́líìtì ẹ̀yẹ WBA,IBF ati WBO, gba àmì ẹyẹ nàá ní ìsọ̀rí àmì ẹ̀yẹ OBE, èyí tí wọ́n n pè ní Order of British Empire..
Láàrin ọdún márùn,Joshua ti gba àmì ẹ̀yẹ méjì, èyí tó túmọ̀ sí pé wọn yòó maa fi ''Sir'' sí iwájú orúkọ rẹ̀.
Anthony Joshua, ọmọ ọdún méjìdínlógún ti gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ àmì ẹ̀yẹ níbi ìjà káàkiri.