You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
World Cup 2018: Orílẹ̀-èdè mẹ́sàn-àn ló ti gba ife sẹ́yìn
Àjọ eléré bọ́ọ́lù lágbàáyé, FIFA, ló ń ṣe agbátẹrù ife ẹ̀yẹ àgbáyé, Ọdún mẹ́rin-mẹ́rin sì ni ìdíje naa máa ń wáyé.
Ìdíje ife ẹ̀yẹ àgbáyé jẹ́ ìdíje láàrin àwọn ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù ọkùnrin láwọn orílẹ̀-èdè káàkiri àgbáyé.
Orílẹ̀-èdè Uruguay ló kọ́kọ́ gba àlejò ìdíje ife ẹ̀yẹ àgbáyé lọ́dún 1930, orílẹ̀-èdè mẹ́tàlá sì ló kópa nínú rẹ̀.
Ọdún 1942 si 1946 nìkan sì ni ìdíje náà kò leè wáyé nítorí ogun àgbáyé tó ń lọ lọ́wọ́ nígbà náà.
Ìgbà ogún ni ìdíje ife ẹ̀yẹ àgbáyé ti wáyé sẹ́yìn. Ìdíje ti ọdún 2018 sì ni yóò sọ ọ di mọ́kànlélógún, èyí tó ń wáyé lọwọ ní orílẹ̀-èdè Russia loṣù kẹfà si oṣù keje, ọdún 2018 bayii, nibi tí àwọn orílẹ̀-èdè bíi mẹ́tàlélógún sì ti n kópa nínú rẹ̀, ó kéré tán, ní ẹ̀ẹ̀kan soso.
Táa bá sì ní ká kàá ní ení, èjì, ọdún kejìdínláàádọ́rùn-ún rèé tí wọn bẹ̀rẹ̀ ìdíje ife ẹ̀yẹ àgbáyé.
Ikọ̀ agbábọ́ọ́lù láti orílẹ̀-èdè méjìlá ló ti dé ìpele àsekágbá ìdíje náà láti ìgbà tó ti bẹ̀rẹ̀, àmọ́ ikọ̀ agbábọ́ọ́lù méjọ péré ló tii gba ife ẹ̀yẹ àgbáyé náà.
Orílẹ̀-èdè Brazil ló tíì se àseyọrí nínú ìdíje ife ẹ̀yẹ àgbáyé jùlọ, tó sì jẹ pé òun náà sì ló tíì farahàn jùlọ nínú gbogbo ìdíje ife ẹ̀yẹ àgbáyé tó ti ń wáyé.
Ọjọ́ Àìkú, ni àsekágbá àwọn ìdíje ife ẹ̀yẹ àgbáyé máa ń wáyé àyàfi ọdún 1930 àti 1966 nìkan tí ìdíje ife ẹ̀yẹ àgbáyé wáyé ní ọjọ́rú àti ọjọ́ àbámẹ́ta.
Titi di ọdún 2014, àwọn orílẹ̀-èdè láti ilẹ̀ Europe àti South Amẹrika ni wọ́n ń figa-gbága nínú àsekágbá ìdíje ife ẹ̀yẹ àgbáyé.
Ẹlẹẹkọkanlelogun ni eyi to n waye lọwọ ni RUSSIA.