You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
World Cup 2018: Ijàkàdì kọ́, Ipele àkọ́kọ́ nínú ìdíje pari!
Èsì ìdíje ti gba omi ẹkún lójú ọpọlọpọ agbábọ́ọ̀lù atawọn olólùfẹ́ wọn ni Russia 2018.
Àrà ọ̀tọ̀ ni ìdíje eré bọ́ọ̀lù FIFA 2018 ń jásí lọ́tẹ̀ yìí.
Àwọn ikọ̀ ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù kọọkan ń ṣe ju bí àwọn èrò ṣe rò lọ nigba ti àwọn miiran n já wálẹ̀ láìròtẹ́lẹ̀. Ìdíje bọọlu ti gba iṣiro lọ́tẹ̀ yìí.
Ìdíje FIFA 2018 ti gbé ojú àwọn agbabọọlu tuntun síta gbàgede.
Awọn wo lo kù?
Bọọlu gbígbá ti di, 'A ju ara wa lọ; ìjàkadì kọ́'!
Ikú to n pa ojúgbà ẹni, òwe nla lo n pa fun ni.
Ipele akọkọ ninu idije ife ẹyẹ agbaye Russia 2018 ti pari.
Awọn orilẹ-ede kan to kogba wọle nigba ti awọn to yege n tẹsiwaju ninu ipele Komẹsẹ- o- yọ-danu.