You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ibà ṣọkọ fún Serena Williams, kò lè kópa ní Madrid open
Àìsàn ibà ti yọwọ́ Serena Williams láwo ìdíje bọ́ọ̀lù Orí Kọnkéré, Lawn tennis nílùú Madrid.
Àwọn alákóso ìdíje náà ló kéde rẹ̀ lọ́jọ́bọ.Serena Williams kéde lórí ìkànnì ayélujára ti ìdíje Madrid Opens pe, " O dùn mí láti yọwọ́ nínú ìdíje Madrid Opens yii nítorí pé, mo ní ibà, ara mi kò jí pépé".Gbajúgbajà òdú agbábọ́ọ̀lù oríi kọn kéré náà kéde àìní kópa rẹ̀ kí ètò ìpín ni sí ìsọ̀rí fún ìdíje náà tó wáyé.
Ní oṣù kẹta ni Serena pada sori papa ni idije bọ́ọ̀lù oríi kọnkéré to wáyé ni Indian Wells ati Miami léyìn tó bímọ.O ṣeéṣe kí Ó padà láti kópa ní idije tí yóò wáyé ní ilu Róòmù, lọ́jọ́ kẹtàlá si ogúnjọ́ oṣù kàrún un
Eyi yoo je ko lè gbáradì fún idije French Open ti yóò wáyé nílùú Paris, lọ́jọ́ kẹtàdínlọ́gbọ̀n oṣù kàrún sí ọjọ́ kẹwàá oṣù kẹfà.Gbajúgbajà ife ẹ̀yẹ mẹtalelogun ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Serena Williams ti gba ninu ìdíje bọ́ọ̀lù oríi kọnkéré lágbáyé.