You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ààrẹ Buhari yóò lọ sèpàdé pẹ̀lú ààrẹ Trump
Àarẹ Muhammadu Buhari yóò tẹkọ̀ òfurufú létí lọ sí orílẹ̀èdè Amẹ́ríkà ní ìbẹ̀wò ìdáhùn sí ìpè ààrẹ Donald Trump láti jọ sèpàdé.
Ìpàdé náà yóò wáyé láti jíròrò lórí ọ̀nà àti mú ìbásepọ̀ tó dánmọ́rán láàrin orílẹ̀èdè mejèèjì àti láti mú ìgbéga bá àwọn ohun tó kàn gbọ̀ngbọ̀n bíì ìlọsíwájú ọrọ̀ ajé, dídojú ìjà kọ sùnmọ̀mí àtàwọn ǹkan míì tó ńdún mọ̀hurumọ̀huru mọ́ àláfíà àti àbò ìlú.
Ìpàdé náà yóò tún mú ìrẹ́pọ̀ láàrin orílẹ̀èdè Amẹ́ríkà àti Nàíjíríà jinlẹ̀ síi gẹ́gẹ́ bí orílẹ̀èdè Amẹ́ríkà se rí ìdàgbàsókè ọrọ ajé Nàíjíríà, àbò àti adarí nílẹ̀ Áfíríkà bí ohun pàtàkì nínú ìlànà àjọsepọ̀ wọn.