You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Anthony Joshua ti na Joseph Parker nibi ìdijé ẹ̀ṣẹ
Anthony Oluwafẹ́m Joshua ti sọ igbanu ẹyẹ ẹṣẹ WBA, IBF ati WBO di ọkan nigba to na Joseph Parker ni papa iṣere Principality nigboro Cardiff.
Ọmọ Yoruba ọhun to jẹ ọmọ orilẹede Gẹẹsi, ẹni ọdun mejidinlọgbọn (28), lo ọwọ osi rẹ dara-dara nigba ija ti Parker to jẹ ọmọ orilẹede New Zealand naa ti lo iyawọ rẹ ati amumọra rẹ bo ti yẹ
Sugbọn o da bi ẹni pe igbanu ẹyẹ WBO rẹ yoo pada si idi Joshua nigba to ri awọn ami ayo pataki nibi ẹṣẹ isalẹ agbọn to gba Parker ni ẹsẹ kejọ ati bo ti fi ẹṣẹ ta bi agbọn ni ẹsẹ kewa idije ija naa.
Lẹyin ọrẹyin ni awọn alakoso ija naa ba panupọ pe Anthony Oluwafẹm Joshua lo bori Joseph Parker.