Ihenacho, Mahrez tan bi oorun bi Leicester se na Westbrom

Nka ṣe ẹnuure fun agbabọọlu ọmọ orilẹede Naijiria ti o n gba bọọlu jẹun pẹlu ikọ Leicester city, Kelechi Ihenacho, lọjọ abamẹta pẹlu bi ikọ rẹ ṣe gbo ewuro si oju Westbrom nibi ifẹsẹwọnsẹ idije liigi premiership to waye laarin Leicester city ati Westbrom.

Nse ni kelechi tan bi oorun ninu ifẹsẹwọnsẹ naa pẹlu bi o se gba bọọlu kan si awọn ti o si tun se atukọ fun goolu miran ninu ifẹsẹwọnsẹ ọhun.

Bakanna ni ọmọ orilẹede Algeria ni, Riyad Mahrez pẹlu gba bọọlu wọle sinu awọn Westbrom nibi ifẹsẹwọnsẹ naa eyi ti Leicester ti jẹwọ alejo ọran fun Westbrom.

Goolu mẹrin si ẹyọkan soso ni Leicester city fi gbẹyẹ mọ Westbrom to n gbalejo rẹ lọwọ eyi to fi ẹsẹ wọn lelẹ bayii ni ipo kẹjọ lori atẹ igbelewọn liigi ilẹ Gẹẹsi fun saa ọdun 2017/2018 to n lọ lọwọ.

Ni isẹju kẹrindinlọgọrin ifẹsẹwọnsẹ yii ni Kelechi Ihenacho fi ori kan bọọlu wọle lẹyin ti Ben Chilwell to jẹ akẹgbẹ rẹ ti gba bọọlu na soke fun loju ile.

Ọmọ orilẹede Naijiria miran , Wilfred Ndidi, pẹlu tayọ ninu ifẹsẹwọnsẹ naa sugbọn ni isẹju kẹtalelaadọrin lo gba kaadi ikilọ fun bi o se kọlu agbabọọlu Westbrom kan.