You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Idije Uefa Europa League: Arsenal ati Atletico fakọyọ
Ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal ati Atletico Madrid fi oju awọn ẹgbẹ agbabọọlu Oestersunds FK ati FC Koebenhavnti gbo'lẹ ninu idije ti Europa League ti o waye kaakiri ilẹ Yuroopu lọjọbọ.
Alex Iwobi wa pẹlu ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal nigbati wọn f'iya jẹ ẹgbẹ agbabọọlu Oestersunds pẹlu amin ayo mẹta si odo.
Nacho Monreal pẹlu Mesut Ozil jẹ ami ayo kọọkan ti Sotirios Papagiannopoulos si gba bọọlu s'awọn ikọ agbabọọlu ara rẹ.
Athletico Madrid pẹlu fi iya jẹ FC Koebenhavnti pẹlu ami ayo mẹrin si ẹyọ kan.
ninu awọn ifẹwọnsẹ miran to waye, AC Milan lu Ludogorets Razgrad, RZ Leipzig naa fi agba han Napoli; bẹẹni Athletic Bilbao ta ọmi pẹlu Spartak Moscow.
Eyi ni esi awọn ifẹsẹwọnsẹ miran ninu idije Europa League:
FC Astana 1 - 3 Sporting CP
Borussia Dortmund 3 - 2 Atalanta
Ludogorets Razgrad 0 - 3 AC Milan
Marseille 3 - 0 Braga
Nice 2 - 3 Lokomotiv Moscow
Oestersunds FK 0 - 3 Arsenal
Real Sociedad 2 - 2 Salzburg
Spartak Moscow 1 - 3 Athletic Bilbao
AEK Athens 1 - 1 Dynamo Kyiv
Celtic 1 - 0 Zenit St. Petersburg
FC FCSB 1 - 0 Lazio
FC Koebenhavn 1 - 4 Atletico Madrid
Lyon 3 - 1 Villarreal
Partizan Beograd 1 - 1 Viktoria Plzen
SSC Napoli 1 - 3 RasenBallsport Leipzig