You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ṣé kìí ṣe pé ìkọlù sí àwọn Kristiẹni ní Naijiria n pọ̀ sí báyìí? Ọ̀pọ̀ èèyàn ń kọminú
- Author, Peter Mwai
- Role, BBC Reality Check
Ipaniyan to waye laipẹ yii ni ile ijọsin ijọ Aguda kan ni ilu Oow, nipinlẹ Ondo, ti mu ki ominu ma a kọ ọpọ eeyan nipa ija ẹsin ni Naijiria.
Ẹgbẹ awọn ọmọlẹyin Kristi, CAN, sọ pe ikọlu to n waye si awọn ṣọọṣi ati awọn Kristiẹni ti n lọ soke pupọ.
Agbẹnusọ ẹgbẹ CAN, Adebayo Oladeji, sọ pe ọrọ naa ti n bọ si ipo ainireti ati ibẹru bojo.
Ikọlu melo lo ti waye?
Nkan to fojuhan ni pe ikọlu si awọn Kristiẹni ti pọ si lati ọdun 2019.
Gẹgẹ bi akọsilẹ iwadii ti ajọ Armed Conflict Location and Event Data Project (ACLED) fi sita, igba mẹtalelogun ni ikọlu ti waye ninu ọgba awọn ṣọọṣi, ati awọn to jẹ Kristiẹni, ninu ọdun 2022 nikan.
Igba mọkanlelọgbọn lo waye lọdun 2021, mejidinlogun lọdun 2020.
Ni ti ọdun 2022, lara awọn ikọlu to ti waye ni:
- Awọn agbebọn pa ogoji olujọsin ni ile ijọsin kan nilu Owo, nipinlẹ Ondo, lọjọ karun-un, oṣu Kẹfa
- Awọn kan tun ji olori ijọ Methodist ni Naijira, Samuel Kanu Uche, gbe ni ipinlẹ Enugu, lọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Karun-un
- Awọn kan tun ji alufaa ijọ Aguda meji gbe nipinlẹ Katsina, lọjọ karundinlọgbọn, oṣu Karun-un.
Ni ọdun mẹwaa sẹyin, ikọlu si awọn Kristiẹni pọ gan-an, pẹlu igba mẹrindinlaadọta lọdun 2012.
Ni oṣu Kẹrin ọdun naa, ko din ni eeyan mẹẹdogun ti awọn agbebọn pa ninu gbọngan fasiti kan ti awọn Kristiẹni ti n jọin nilu Kano.
Ko pẹ si asiko naa ti eeyan mọkandinlogun tun ku nibi ikọlu kan to waye ni ṣọọṣi kan ni aarin gbungbun Naijiria.
Lasiko naa, pupọ ninu awọn ikọlu ọhun lo wa lati ọwọ ikọ alakatakiti ẹsin Islam, Boko Haram.
Awọn akọsilẹ ti ajọ ACLED lo, wa lati ọwọ awọn ẹlẹgbẹjẹgbẹ ni Naijiria ati awọn ileeṣẹ iroyin, eyi to tumọ si pe ọpọ iṣẹlẹ lo ṣe e ṣe ko ma si akọsilẹ fun.
Bakan naa lo tun ṣoro lati sọ pato iye eeyan to ku ninu awọn ikọlu to waye si awọn Kristiẹni.
Ṣugbọn lati asiko diẹ sẹyin, ajọ ACLED sọ pe ikọlu to n waye si awọn Kristiẹni, la tun gbọdọ wo gẹgẹ bi ikọlu si awọn araalu, lafi ti ẹsin wọn ṣe - ni Naijiria lati ọdun 2020.
Diẹ lara awọn ikọlu naa lo wa lati ọwọ awọn alakatakiti ẹsin Islam bi Boko Haram, si awọn Musulumi miran ti wọn ri bi ẹni pe wọn ko ṣe Islam bi i ti wọn.
Awọn ile ẹkọ ti wọn ti n kọ awọn ọmọbinrin to jẹ Musulumi, wa lara awọn ibi ti wọn kọlu, ti wọn si gbe awọn ọmọ lọ. Wọn tun kọlu awọn olori ẹsin Islam to sọrọ tako iṣẹ buruku awọn agbebọn naa.
Akọsilẹ ACLED sọ pe awọn oloṣelu ati awọn obinrin lo pọ ju ninu awọn ti wọn n jigb laarin ọdun 2018 si ipari oṣu Kẹrin, ọdun 2021.
Ta a lo n ṣe awọn ikọlu to n waye lasiko yii?
Ikọ agbebọn kan to ni ibaṣepọ pẹlu ẹgbẹ agbesunmọmi Islamic State, ni awọn alaṣẹ Naijiria fura si pe o ṣe ikọlu si ile ijọin awọn Kristiẹni nipinlẹ Ondo.
Botilẹ jẹ pe awọn ẹgbẹ agbebọn to jẹ alakatakiti ẹsin Islam ti kọlu awọn Kristiẹni fun ọpọ ọdun, awọn ẹgbẹ agbebọn mii ti ko ni ibaṣepọ pẹlu ẹgbẹ kankan naa n ṣe ikọlu, wọn tun n ji ẹran ọsin ati dukia .
Ọrọ naa tun ruju nitori ija to n waye ni gbogbo igba laarin awọn darandaran ati awọn agbẹ nitori ilẹ.
Ninu awọn ija yii, ikọlu ko yọ awọn ilu to jẹ ti ẹsin Kristiẹni ati Islam silẹ - ile ati ile ijọsin ni wọn kọlu.
Kini ijọba ti sọ lori iṣẹlẹ yii?
Aarẹ Muhammadu Buhari ti ṣaaju di ẹbi awọn ikọlu naa ru awọn to n gbero lati da wahala silẹ lagbo oṣelu, ti wọn si fẹ fa ipinya ni Naijiria nitori ẹsin.
Bakan naa, ọga agba ọlọpaa, Usman Alkali Baba, paṣẹ pe ki iwadii to jinlẹ waye lori iklu to ṣẹlẹ nipinlẹ Ondo, lati le mu awọn to ṣe e.
Awọn ẹgbẹ Kristiẹni sọ pe awọn igbesẹ ti ijọba n gbe lo mu ki ọrọ naa buru bẹẹ.
Agbẹnusọ fun CAN, Ọgbẹni Oladeji sọ pe eto idari ati ijọba n ṣe fun awọn agbebọn to ba ronupiwada, to si tun n da wọn pada si aarin ilu, ko so eso rere.
Pasitọ James Wuye, olori ibudo kan to wa fun onirruru ẹsin, nilu Kaduna, sọ pe ijiroro pẹlu awọn ọdọ ni Naijiria, ati awọn eeyan lati gbogbo ẹsin ni ọna abayọ.
Akẹẹgbẹ rẹ, Imaamu Muhammad Ashafa, sọ pe Naijiria nilo lati ni oye kikun pe "iwa ipa ko yanju isọro kankan ri".
Awọn mejeeji kesi ijọba pe ko ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn olori ẹsin, lati ṣe ofin ti yoo mu ki ifarada wa lagbo ẹ̀sìn.
Pasitọ Wuye sọ pe "ofin yoo fi iya jẹ awọn olori ẹsin to ma n ṣe igbelarugẹ ati atọkun fun iru awọn ikọlu bẹẹ".