Osun PDP primaries: Ilé ẹjọ́ wọ́gílé ìdìbò tó gbé Ademola Adeleke wọlé gẹ́gẹ́ bí olùdíjé PDP ní Osun

Ile ẹjọ giga kan to wa ni ilu Ijebu-Jesa ti fidi rẹ mulẹ pe Dotun Babayemi ni ojulowo oludije ẹgbẹ oṣelu Peoples' Democratic Party ninu idibo gomina Osun.

Ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kẹjọ, oṣu Kẹta, ọdun 2022, ni ẹgbẹ oṣelu PDP ṣeto idibo abẹle lọna meji ọtọọtọ nibi ti Ademola Adeleke ati Dotun Babayemi ti jẹyọ̀ bi oludije fun ipo kan naa.

Adedokun Ademola ati eeyan mọkandinlọgbọn mii lo pe ẹjọ tako ẹgbẹ PDP ati ajọ eleto idibo, INEC.

Adajọ ile ẹjọ naa, Onidajọ Adeyinka Aderibigbe sọ pe awọn aṣoju ẹgbẹ to dibo yan Babayemi, ṣe bẹẹ ni ibamu pẹlu idajọ ile ẹjọ to waye lọjọ kejilelogun, oṣu Kọkanla, ọdun 2021.

Ati aṣẹ ti ile ẹjọ pa lọjọ kẹta, oṣu Kẹta, ọdun 2022 pe okoolerugba din marun-un awọn olori ẹgbẹ ni wọọdu ti wọn dibo yan nigba naa nikan lo ni ẹtọ lati dibo gẹgẹ bi aṣoju nibi ti wọn ti yan oludije.

Ile ẹjọ ti wa paṣẹ pe idibo to gbe Babayemi wọle gẹgẹ bi oludije ni ẹgbẹ oṣelu PDP ni ipinlẹ Osun, ati ajọ INEC gbọdọ tẹwọ gba.

Bakan naa lo wọgile gbogbo eto ati igbesẹ to waye lai bọwọ fun aṣẹ t'ile ẹjọ pa lọjọ kejilologun, oṣu Kọkanla, ọdun 2021.

Ọjọru, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kẹta ni igbẹjọ yoo tẹsiwaju.