Marriage Divorce: Ilé ẹjọ́ tú ìgbéyàwó ọdún mẹ́sàn ka lẹ́yìn tí ọkọ fi ẹ̀sùn olè jíjá kan ìyàwó

Ile ẹjọ ibilẹ kan to wa ni adugbo Mapo nilu Ibadan ti tu igbeyawo ọlọdun mẹsan kan ka nitori ẹsun ole jija ti ọkọ fi kan iyawo rẹ.

Aarẹ ile ẹjọ naa, Oloye Ademola Odunade tu igbeyawo naa ka lẹyin ti ọkọ, Ọgbẹni Olanrewaju Olaopa rojọ niwaju ile ẹjọ pe iyawo oun, Tolulope n jale, o si tun n ṣe agbere.

Olanrewaju fi ẹsun kan Tolulope pe o ji tolotolo nla meji ti wọn le ta ọkọọkan ni ẹgbẹrun mẹẹdogun Naira, gbe ninu oko oun lasiko ti oun ko si nile.

O sọ pe o tun ji ẹrọ amohunmaworan ati faanu gbe ninu oko oun.

Amọ ṣa, nigba to n f'esi si ẹsun ti ọkọ rẹ fi kan an, Tolulope sọ pe oun gbe tolotolo mejeeji nitori pe ọkọ oun ko san owo oṣu ko ti i san owo iṣẹ oun gẹgẹ bi alamojuto oko nkan ọsin abiyẹ naa.

Bakan na ni iya ọkọ fi ẹsun kan Tolulope pe "o maa n lu oun, o si tun ti l'eri-leka lati fun oun, ọmọ oun ati awọn ọmọọmọ oun mejeeji ni majele jẹ.

Lẹyin gbogbo atotonu, Tolulope gba pe ki ile ẹjọ tu igbeyawo wọn ka.

Ninu idajọ rẹ, Oloye Odunade tu igbeyawo naa ka, o si fi amojuto awọn ọmọ wọn mejeeji le Tolulope lọwọ.

Bakan naa lo paṣẹ fun Olanrewaju lati maa san ẹgbẹrun mẹwa Naira fun Tolulope loṣooṣu gẹgẹ bi owo ounjẹ awọn ọmọ wọn.

Yoo si tun maa san owo ileewe ati gbogbo nkan ti wọn ba nilo.