You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
H R: Èwo ló ṣe pàtàkì jù nínú ọjọ́ orí àti ìrírí?
Ile igbimọ aṣojusofin Naijiria ti n gbe igbesẹ lori ofin kan ti yoo fi opin si fifi iṣẹ dun ni nitori ọjọ ori lawọn ileeṣẹ ijọba apapọ, laifi ṣe pe wọn koju oṣunwọn fun iṣẹ naa.
Eyi si jẹ́ ohun to tun wọpọ ni awọn ileeṣẹ̀ aladani l'orilẹ-ede Naijiria, paapaa bi ọpọ agbaniṣiṣẹ ṣe maa n fi gbedeke si ọjọ ori awọn ti wọn fẹ ẹ gba siṣẹ.
Sugbọn saa, kini ọjọ ori niiṣe pẹlu iṣẹ wiwa? Onimọ nipa eto igbanisiṣẹ ati iṣẹ ṣiṣe, Ajọkẹ Temitọpẹ Samuel-Anya ba BBC Yoruba sọrọ.
O sọ pé ọpọlọpọ ọ̀dọ́ Naijiria ni ko poju owó to lati gba siṣẹ lasiko yii.
O ṣalaye wi pe ọjọ ori kii ṣe idiwọ lati ri iṣẹ. Sugbọn nigba mi, gbigbanisisẹ maa n niise pẹlu iru iṣẹ ti wọn fẹ gba wọn si.
"Isẹ to ba niise pẹlu gbigbe nkan, gigun nkan, wọn le maa gba ẹni ti o ti dagba, nitori pe o le ma ni okun ati agbara lati ṣe iru iṣẹ bẹ.
O sọ pe lootọ ni ofin osisẹ ni Naijiria ko sọ nipato ọjọ ori ti wọn le fi gba eeyan sisẹ, sugbọn ofin ilẹ okeere ko fi aaye gba idẹyẹsi.
Ko yẹ ki idẹyẹsi wa."
Ọjọ ori tabi pipoju owo fun iṣẹ́?
Ajọkẹ Samuel-Anya sọ pe ko tọ fun awọn ileeṣẹ lati maa fi gbedeke si ọjọ ori awọn to le kọwe beere fun iṣẹ sinu ikede wọn, nitori eyi le mu ki iru ileeṣẹ bẹ ẹ padanu ẹni to yẹ.
"Ọrọ igbanisisẹ ti kuro ni ọrọ ọjọ ori, bi ko ṣe bi ẹniti wọn fẹ gba sisẹ ṣe dangajia si tabi to le fun ileeṣẹ ni abajade esi ti wọn n wa.
Gbogbo eniyan gbọdọ ni anfaani kan na lati kọwe beere fun iṣẹ."
Kini ẹni 'to ti dagba ju fun iṣẹ' le ṣe?
Wa idagbasoke fun ara rẹ. Gbiyanju lati wa imọ kun imọ, ki o si fira rẹ si ipo ti yoo mu ọ yege tabi dayatọ laarin awọn ti wọn jọ fẹ ẹ gba iṣẹ.
Ma se sọ ireti tabi dara nu pe mo kuku ti dagba kọja ẹni ti wọn n fẹ.
Bi o ṣe polowo ara rẹ ninu iwe igbanisisẹ rẹ, ati iwe to n sọ nipa iriri rẹ (Curriculum Vitae) rẹ ni yoo sọ boya o ri iṣẹ tabi o ko ni i ri gba.
Ohun kan soso ti o nilo ni ki ẹnikan gbagbọ ninu rẹ.
Ta a lo n ri iṣẹ ju, ọdọ tabi agbalagba?
Nigba ti a beere lọwọ rẹ gẹgẹ bi onimọ, pe ta a lo tete n ri iṣẹ gba ju ninu awọn ọdọ̀ ati awọn to ti dagba l'orilẹede Naijiria, Ajọkẹ Samuel-Anya ṣọ pe awọn agbalagba lo n ri iṣẹ ju lati ara ohun ti oun ti ri.
"Ọpọlọpọ awọn ọdọ ti mo ti fi ọrọ wa lẹnu wo ni ko pojuowo, o si maa njẹ ibanujẹ fun mi pe awọn akẹkọ jade ileewe giga ko le kọ nkan daada.
Ọpọlọpọ wọn ko ti lẹ mọ bi wọn ṣe n polowo ara wọn fun awọn agbanisiṣẹ."
Lootọ o le jẹ nitori eto ẹkọ, sugbọn iwọ gẹgẹ bi ẹni kan ko gbọdọ duro soju kan. Awọn to n ri iṣẹ gba n dagba si l'ojoojumọ nipa ọgbọn, imọ, oye ati eero wọn.
Ọrọ iṣẹ wiwa ti kuro ni pe mo kan n wa ọna lati maa ri owo gbọ bukata nikan. Biko se pe ki gan an lo ni lati fi ṣanfaani fun ileeṣẹ to fẹ gba ọ siṣẹ.