You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Àwọn àpẹẹrẹ mẹ́sàn-án tí yóò fihàn pé o ti n darúgbó
"Ko si nkankan ninu ara wa to n dara si bi a ba ṣe n dagba."
Wọnyii ni ọ̀rọ̀ to jade lẹnu Dokita Manuel Serrano, to n sisẹ ni ileewosan National Centre for Oncological Investigations, ni Spain.
O jẹ ọkan lara awọn to kọ aabọ iwadi kan - Awọn apẹrẹ pe o ti n darugbo - ninu eyi ti awọn oniwadii ti ṣe akọsilẹ awọn nkan gboogi to n waye ninu ara wa ni ojoojumọ.
O sọ pe ti ẹnikan ko jọ ti ẹnikeji - nitori igbeaye ti ẹnikọọkan n gbe, sugbọn wọn ko le ṣe alaisẹlẹ.
Awọn nkan mẹsan an to maa n fihan pe o ti n darugbo niyii - lara ẹranko ati eniyan
1. Awọn nkan to ti bajẹ ninu eroja ajogunba, DNA, yoo ma pọ si
Awọn nkan ti a jogunba latara obi, DNA, jẹ akojọpọ awọn eroja ti o n lọ lati sẹẹli ara kan si ikeji. Ti awọn eroja DNA yii ko ba ṣiṣẹ bo se yẹ mọ, o le ṣe akoba fun bi awọn sẹẹli ara ṣe n ṣiṣẹ. Ti eyi ba si n ri bẹ, o le sọ awọn sẹẹli naa di nkan to le fa jẹjẹrẹ.
2. Eroja kromosoonu yoo da iṣẹ silẹ
Awọn eroja DNA ni ideri kan to n bo awọn kromosoonu wa.
Wọn n pe wọn ni telomeres. Bi a ṣe n dagba, awọn ideri naa n gbo, aabo si n sọnu fun awọn kromosoonu naa.
Iwadi awọn onimọ sayẹnsi sọ pe bi a ṣe n dagba ni awọn eroja ara yi n ku, to si n fa wahala fun agọ ara wa.
Ati pe a le fi kun akoko ti telomeres yoo lo lara, eyi ti yoo si fi kun ọjọ aye wa - wọn ti dan an wo lara ekute.
3. Awọn sẹẹli ara maa n pin iṣẹ fun ara wọn
Ara wa maa n ṣiṣẹ kan - o maa n pin iṣẹ fun awọn sẹẹli, lati jẹ ki kaluku mọ ibi ti yoo ti ṣiṣẹ ninu ara.
Akoko ati igbeaye le ṣe idiwọ fun aṣẹ ti ara ba pa a.
Eyi si maa n mu ki awọn sẹẹli ṣiṣẹ kiṣẹ.
4. Ao sọ agbara lati tun awọn sẹẹli wa ṣe nu
Ara wa ni agbara lati dena ki awọn ẹya to ti bajẹ pọ ninu sẹẹli wa.
Ṣugbọn agbara naa maa n dinku bi a ṣe n dagba si.
5. Awọn sẹẹli ko ni le ṣiṣẹ daada lori ounjẹ ti a n jẹ mọ
Bi ọjọ ṣe n gori ọjọ ni awọn sẹẹli n sọ agbara lati lọ awọn eroja ounjẹ bi i ọ̀rá ati ṣuga nu
Eyi si le yọri si aisan itọ ṣuga. Idi si niyii ti aisan itọ suga to waye nipasẹ ọjọ ori fi wọ́pọ̀ - ara to ti darugbo ko le ṣiṣẹ lori gbogbo awọn ounjẹ to wọ inu rẹ.
6. Eroja Mitochondria ko ni ṣiṣẹ mọ
Ẹya ara ti wọn n pe ni Mitochrondria lo n fun awọn sẹẹli l'agbara, ṣugbọn wọn maa n sọ agbara ti wọn naa nu bi ọdun ṣe n gori ọdun.
Ti wọn ba ti n ṣiṣẹ kiṣẹ, o le ṣe akoba fun DNA.
Awọn iwadi kan fihan pe ṣiṣe atunṣe bi mitochondria ṣe n ṣiṣẹ le fikun ọdun ti awọn nkan abẹmi bi eniyan yoo lo.
7. Sẹẹli ko ni ji pepe mọ
Ti sẹẹli ba ti bajẹ ju boṣeyẹ lọ, ko ni ṣiṣẹ mọ, ko maa ba pese awọn sẹẹli mi i ti ko dara.
Sẹẹli ti ko ji pepe mọ naa le ṣe akoba fun awọn sẹli to ku, o si le fa a ki gbogbo ara o wu.
Ayẹwo ti wọn ṣe fun eku fihan pe yiyọ awọn sẹẹli naa le mu adinku ba ipa ti didarugbo n ni lara.
8. Awọn sẹẹli ara yoo sọ agbara wọn nu
Adinku to maa n deba awọn eroja to n sọ ẹya ara di titun jẹ ọ̀kan lara apẹrẹ pe o ti n darugbo.
Iwadi fihan pe sisọ awọn sẹẹli ara di titun ṣeese ki adinku ba bi ara se n fihan pe oun ti n dagba.
9. Awọn sẹẹli ko ni ba ara wọn ṣepọ mọ
Awọn sẹẹli maa n ba ara wọn ṣepọ loorekoore, ṣugbọn eyi maa n dinku to ba ya.
Eyi si maa n yọri si ki wọn o wu, ibasepọ wọn si maa n dinku.
Lootọ ni ko ṣeeṣe ko maa waye, ṣugbọn gbigbe igbeaye ilera to peye le dinku.