Ìjọba Amẹrika ṣe àtúnṣe òfin Físà gbígbà, wo bó ṣe kàn ọ́

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ijọba ilẹ Amẹrika ti ṣatunṣe si ofin to de fisa gbigba fun awọn to ba fẹ rinrinajo lọ silẹ naa lati asiko yii lọ.

Ofin tuntun naa sọ pe gbogbo ẹni to ba fẹ gba fisa ni iṣọri ti ọrọ naa kan gbọdọ ṣe ifọrọwanilẹnu ni ileeṣẹ ijọba Amẹrika to wa lorilẹede wọn tabi ni orilẹede ti wọn n gbe.

Awọn ti ọrọ naa kan ni awọn to ba fẹ gba fisa to wa ni iṣi 'non-immigrant visa' ti ọpọ mọ si B1/B2.

Ọọfisi ijọba Amẹrika, US Department of State sọ pe lẹsẹkẹsẹ ni aṣẹ yii yoo bẹrẹ si ni mulẹ.

Wọn ni aṣẹ tuntun yii bori awọn aṣẹ to ti waye ṣaaju lori ọrọ fisa gbigba.

Ninu atẹjade kan loju opo ọọfisi ijọba Amẹrika, o ni "Awọn ọmọ orilẹede ti ijọba Amẹrika kii ṣeto fisa fun loorekoore, gbọdọ kọwe ẹbẹ fun fisa naa ayafi ti wọn ba n gbe nibomii.

Lara awọn orilẹede ti wọn kede pe wọn wa ni iṣi yii lawọn orilẹede ti ogun n ja bii Afghanistan (Islamabad), Belarus (Vilnius, Warsaw), Cuba (Georgetown), Iran (Dubai), Russia (Astana, Warsaw), Venezuela (Bogota), ati Yemen (Riyadh).

Awọn ayipada mẹta mii ti ijọba Amẹrika kede lori fisa gbigba

  • Ibi ti eeyan n gbe: Wọn ni awọn to n kọwe fun fisa gbọdọ ṣafihan pe wọn n gbe ni orilẹede ti wọn ti n kọwe ẹbẹ fun fisa naa
  • Owo fisa sisan: O le ṣoro fun awọn to ba n kọwe fun fisa lati orilẹede mii ti kii ṣe orilẹede wọn lati ri fisa naa gba, ijọba Amẹrika ko si ni da owo fisa ti wọn san ṣaaju pada fun wọn
  • Akoko ifọrọwanilẹnuwo: Awọn to ba fẹ gba fisa amọ ti wọn forukọsilẹ ni orilẹede mii yatọ si orilẹede wọn gbọdọ ni suuru fun akoko pipẹ ki ifọrọwanilẹnuwo to kan wọn

Atẹjade naa ṣalaye siwaju si pe ayipada ko ni de ba awọn ti wọn ti mu ọjọ ifọrọwanilenuwo wọn ṣaaju atunṣe tuntun yii.

Wọn fi kun pe wọn le fi alafo silẹ fun awọn to nilo fisa latari eto ilera wọn tabi awọn to jẹ aṣoju ijọba orilẹede.

Lẹyin naa ni wọn gba gbogbo awọn arinrinajo niyanju lati maa wo oju opo ọọfisi naa loorekoore fun awọn iroyin to yẹ ki wọn mọ nipa fisa gbigba.

Iroyin ni atunṣẹ tuntun yii ko ṣẹyin bi awọn eeyan kan ṣe maa n rinrinajo lọ si orilẹede mii yatọ si orilẹede wọn lati kọwe fun fisa Amẹrika.

Fun apẹrẹ, ti ko ba si aye fun ifọrọwanilẹnuwo ni ọọfisi ijọba Amẹrika to wa niluu Eko ati Abuja, awọn kan maa yan lati tẹkọ leti lọ si awọn orilẹede mii bii Cameroon, Namibia, Ghana, Ivory Coast, Canada, tabi Dominican Republic ki ifọrọwanilẹnuwo wọn le ya kankan.