You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Rhodes-Vivour olùdíje sípò gómìnà tẹ́lẹ̀ fẹ́gbẹ́ òṣèlú Labour Party darapọ̀ mọ́ ADC l'Eko
Gbadebo Rhodes-Vivour, oludije sipo gomina fẹgbẹ oṣelu Labour Party ninu idibo ọdun 2023 nipinlẹ Eko ti darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu African Democratic Congress (ADC).
Rhodes-Vivour kede igbesẹ rẹ nibi eto kan niluu Eko lanaa ọjọ Abamẹta ọjọ kẹfa oṣu Kẹsan an yii.
Igbesẹ yii ko ṣẹyin bi ẹgbẹ oṣelu ADC ṣe n fa awọn oloṣelu lati inu oniruuru ẹgbẹ mọra lati koju APC ninu eto idibo ọdun 2027.
Loṣu Keje to kọja lawọn oloṣelu lati inu oriṣiiriṣii ẹgbẹ ni Naijiria kora jọ pọ ti wọn si da ẹgbẹ ADC silẹ.
Ninu ọrọ rẹ, Rhodes-Vivour sọ pe ''inu mi dun lati darapọ mọ ẹgbẹ ADC, mo si n foju sọna si irufẹ iṣejọba ti ẹgbẹ oṣelu yii yoo gbe kalẹ ni Naijiria.
Adura mi ni pe Ọlọrun yoo fawọn adari ẹgbẹ wa ni imọ ati ọgbọn lati fi orilẹede Naijiria le ọna to dara lati tọ.
Ikorojọpọ yii waye lati ja Naijiria gba ni, a gbọdọ ṣiṣẹ pọ ki a le lagbara lati doola Naijiria ninu eto idibo ọdun 2027.''
Ṣaaju ni Rhodes-Vivour ti kọkọ fẹsun kan awọn ọlọpaa lọjọ Ẹti to kọja wi pe wọn fẹ da eto to fẹ fi kede igbesẹ rẹ ru ni ijọba ibilẹ Alimosho.
Olalekan Anjolaiya to jẹ oludamọran Rhodes-Vivour sọ ninu atẹjade kan to fi sita pe awọn ti sọ fun ileeṣẹ ọlọpaa tẹlẹ nipa eto ọhun.
Amọ, iroyin fidi rẹ mulẹ pe awọn ọlọpaa ko jẹ ki Rhodes-Vivour atawọn ololufẹ rẹ raye wọle sibi ti wọn fẹ lo fun eto ọhun laarọ ọjọ Abamẹta ki wọn to lọ ṣe eto naa nibo miran.
Rhodes-Vivour ni oun si maa bawọn akọroyin sọrọ lori nnkan to ṣẹlẹ to ba ya, ṣugbọn nnkan to ṣe pataki foun bayii ni pe oun ti darapọ mọ ẹgbẹ osẹlu ADC.
''Awọn eekan ninu lagbo oṣelu ni Naijiria lo n darapọ mọ ADC''
Ẹwẹ, alaga ẹgbẹ ADC nipinlẹ Eko, Ọgbẹni George Ashiru, sọ pe bi Rhodes-Vivour ṣe darapọ mọ ẹgbẹ naa yoo jẹ ki ẹgbẹ oṣelu alatako lagbara sii ṣaaju eto idibo ọdun 2027.
''Awọn eekan lagbo oṣelu ni Naijiria lo n darapọ mọ ADC lonii.
Kii ṣe ẹnikan ṣoṣo lo n darapọ mọ wa, ijọ eeyan lo n darapọ mọ ADC lonii.
Gbogbo ẹgbẹ lo maa n ni olori, olori awọn eeyan to mi ipinlẹ Eko titi ninu eto idibo to lọ ni Gbadebo Rhodes-Vivour jẹ.
Igbakeji Aarẹ Naijiria tẹlẹ, Atiku Abubakar, ti Ọjọgbọn Ola Olateju ṣoju rẹ nibi eto naa rọ awọn ọmọ ẹgbẹ ADC lati pese eto iṣejọba gidi mii to dara fawọn ọmọ Naijiria.
''Ẹ ma jẹ ka wo ara wa bi ẹni ti ko lagbara lati doola orilẹede Naijiria, ko si ẹni ti ko le ṣe iṣẹ to wa nilẹ yii.
ADC kii ṣe ẹgbẹ oṣelu lasan, ẹgbẹ awọn eeyan ni, ipinnu wa ni lati doola orilẹede Naijiria,'' Atiku lo sọ bẹẹ.