You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
DSS fún iléeṣẹ́ ìtàkùn ayélujára X ní ọjọ́ kan láti yọ ọ̀rọ̀ tí Sowore sọ tako Tinubu kúrò, Sowore yarí
Ajọ ọtẹlẹmuyẹ DSS ti kọ iwe si ileeṣẹ itakun ayelujara X tawọn eeyan mọ si Twitter tẹlẹ pe ko yọ oju opo ajafẹtọọ ọmọniyan, Omoyele Sowore, kuro lori itakun naa latari ọrọ kan to sọ eyi ti DSS ni o tabuku orilẹede Naijiria, o si tun le ṣakoba fun eto abo Naijiria.
Ninu lẹta ti DSS kọ si ọga agba ileeṣẹ X ni Texas lorilẹede Amẹrika lọjọ kẹfa oṣu Kẹsan an yii lo ti fẹsun kan Sowore pe o tabuku Aarẹ Bola Tinubu pẹlu ọrọ to fi lede loju opo X rẹ.
Ajọ DSS ni lalẹ ọjọ kẹẹdọgbọn oṣu Kẹjọ to kọja ni nnkan bii aago mọkanla kọja iṣeju mejidinlogoji ni Sowore fi ọrọ naa lede loju opo rẹ.
Ọrọ ti Sowore fi lede naa lo sọ pe ''ọdaran @officialABAT lọ si orilẹede Brazil lati lọ sọ pe ko si iwa ajẹbanu mọ labẹ ijọba oun ni Naijira.
Igboya nla leyii lati parọ lai tiju rara!
Ninu lẹta naa ti Ọgbẹni B. Bamgboye buwọlu lorukọ ọga agba DSS ni ajọ naa ti ṣalaye wi pe kii ṣe oju opo Tinubu @officialABAT nikan ni Sowore doju ọrọ rẹ kọ, bi ko ṣe pe o tun ṣi ọpọ eeyan lọna.
Ajọ DSS fikun ọrọ rẹ pe nnkan ti Sowore sọ jẹ iwa ipa si ẹlomiran lori ayelujara, bakan naa si ni ọrọ ọhun le da rogbodiyan silẹ.
DSS tun sọ ninu lẹta naa pe ọpọ eeyan lo ti bu ẹnu ẹtẹ lu ọrọ ti Sowore fi lede loju opo X rẹ yii, koda, ''awọn alatilẹyin Aarẹ Tinubu kan ti n ṣe ifẹhonuhan loju popo.''
Ajọ ọtẹlẹmuyẹ ni ọrọ ti Sowore sọ lodi si nnkan ti iwe ofin Naijiria ẹka 51 ati isọri 19, 22 ati 24 sọ lori iwa ọdaran.
DSS ni ẹni to sọrọ ati ẹni to gbe ọrọ naa jade le foju wina ofin gẹgẹ bi ofin Naijiria ṣe ṣalaye.
''Idi niyi ti a fi kọ iwe si ileeṣẹ yin lati yọ ọrọ naa kuro ati ibi kibi ti wọn ba ti pin ọrọ naa de lori ayelujara.
Ti ẹ ba kọ lati ṣe bẹẹ laarin wakati mẹrinlelologun, ajọ DSS yoo gbe igbesẹ to lagbara lori ọrọ naa,'' DSS ṣalaye.
Ajọ DSS ni Sowore ti tabuku aarẹ Naijiria laarin awọn orilẹede agbaaye, bakan naa lo si tun ti ṣakoba fun orukọ ati eto abo Naijiria.
Mi o ni yọ ọrọ ti mo sọ loju opo X mi kuro laelae – Sowore
Ẹwẹ, Sowore ti fesi wi pe oun ko ni yọ ọrọ toun fi lede loju opo X kuro.
Sowore, to sọ eyi di mimọ loju opo x rẹ lọjọ Aiku ọjọ keje oṣu Kẹsan an yii sọ pe ileeṣẹ X ti kan si oun, wọn si sọ pe ajọ DSS fẹjọ oun sun pe pe ọrọ toun fi lede loju opo X oun tabuku aarẹ Naijiria.
Sowore ni ko jọ oun loju pe ajọ DSS kọ lẹta lai ni itiju si ileeṣẹ X lati yọ oju opo oun kuro lori itakun ayelujara X laarin wakati mẹrinlelogun.
Ajafẹtọọ ọmọniyan naa ni igbesẹ ajọ DSS lodi sofin, ati pe ofin ti ara wọn ni ijọba to wa lode n tẹle kii ṣe iwe ofin Naijiria.
Sowore ni awọn ọlọpaa ni ijọba ti n lo lati fiya jẹ oun ati lati dunkoko mọ oun.
O ni igbesẹ DSS lati kọ iwe si ileeṣẹ X l'Amẹrika fi han pe alainitiju lawọn ẹṣọ ọtẹlẹmuyẹ to yẹ ko maa wa ojutuu si eto abo Naijiria to mẹhẹ.
''Mi o ni yọ ọrọ ti mo sọ danu, koda, bi mi o ba ni oju opo X ati Facebook mọ, tabi ti mo ba wa lẹwọn, n ko ni dẹkun bi mo ṣe n gbogun ti iwa ibajẹ,'' Sowore lo sọ bẹẹ.