Ṣé N70,000 tó ná fún àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba?

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Lọjọbọ ọsẹ to kọja, Aarẹ Bola Tinubu ati ẹgbẹ oṣiṣẹ lorilẹede Naijiria fẹnuko lori owo oṣu tuntun, eyi to jẹ N70,000 fun awọn oṣiṣẹ.

Eyi tumọ si pe afikun ti ba iye owo oṣu awọn oṣiṣẹ lasiko yii.

Afikun yii waye lẹyin ti ọpọ awọ ti waye laarin ijọba apapọ ati ẹgbẹ oṣiṣẹ lorilẹede Naijiria.

Sugbọn lọwọ yii, orilẹede Naijiria n koju ọpọ ọwọngogo, ti eto ọrọ aje si mẹhẹ ni lo bi ibeere pe n jẹ owo oṣu tuntun yii to awọn oṣiṣe na

Lati igba ti ijọba labẹ Aarẹ Bola Tinubu ti yọ owo iranwọ epo bẹntiro lọdun to kọja ni ọwọngogo ti gbode lorilẹede Naijria

Ibeere pe n jẹ owo oṣu yoo tan iṣoro awọn oṣiṣẹ ni ọpọ awọn eeyan n bi ara wọn bayii

"Owó oṣù tuntun kéré púpọ̀, kò ká nǹkankan"

BBC ba ọpọ awọn oṣiṣẹ ijọba sọrọ lati mọ ero ọkan wọn.

Oṣiṣẹ ijọba to ba BBC sọrọ niluu Abuja ṣalaye pe fun awọn oṣiṣẹ to n sisẹ niluu Abuja sugbọn ti wọn n gbe ni Suleja, owo oṣu naa kere fun wọn.

O ni fun awọn mọlẹbi kan to jẹ pe baba bi ọmọ pupọ, owo oṣu tuntun naa ko ka nkankan rara.

“Sẹ ri emi, ti n ko bimọ pupọ, fun emi, ko si wahala, mo le gbe igbeaye to rọnu pẹlu 70,000.”

Mustapha Muhammad, oṣiṣẹ ijọba nipinlẹ Kano, sọ pe owo oṣu tuntun ko ka nkankan rara.

“Owo apo irẹsi wọn ju owo oṣu lọ, ẹ jẹ ka ni mo n ra apo irẹsi loṣu, ki ni yoo ku lọwọ mi?

”Ki ni ma fi ra awọn nnkan mi tabi wọ ọkọ lọ ibi iṣẹ mi?”

Abubakar Isiyaku, oṣiṣẹ ijọba ati agbẹ nipinlẹ Kaduna ni afikun owo yii ni ko to ọpọ awọn oṣiṣẹ lati na rara.

“Ti ẹ ba wo bi nnkan se ri lọwọ yii lorilẹede Naijiria, bi ọwọngogo se ba gbogbo nnkan, apo irẹsi wọn jẹ N65,000, apo agbado jẹ N80,000 nitori ọwọn gogo ọkọ.

“O yii ko le to oṣiṣẹ lati le ni anfani lati se iṣẹ to yẹ ko ṣe.”

Ki ni awọn akọsẹmọsẹ sọ lori ọrọ owo oṣu tuntun?

Nigba to n sọrọ lori mohunmaworan kan, ọnimọ nipa isiro, Seun Onigbinde ni owo oṣu tuntun ko ba ni iyi to ba jẹ pe ijọba le wa ojutu si ọwọngogo to gbode.

“Owo yii ko to awọn oṣiṣẹ ni ero temi sugbọn aṣeyọri nla ni”

O tẹsiwaju pe oun ko ro pe afikun owo oṣu yii yoo mu aye rọrun tabi adikun ba inira ti awọn araalu n lakọja.

“Afikun yii ko gbo owo lori bi mo ṣe lero. Gbogbo erongba mi ni 100,000 ati 120,000 nitori bi nnkan se buru lọwọ yii ti ẹ ba ọwọngogo.

“Sugbọn Ijọba ti ni ijororo lroi ọrọ owo oṣu lẹyin ọdun mẹta.

Ninu ọrọ tiẹ, Dokita Ahmed Adamu ti fasiti Nile niluu Abuja ni owo oṣu yii yoo tun se akoba nla fun owo naira si.

“Igbe aye ti awọn oṣiṣẹ n gbe lasiko ti wọn n gba 30,000 naa ni wọn n gbe lọwọ nitori ọwọngogo.

O fikun pe awọn ọlọja yoo tun fowokun owo ọja nitori afikun owo oṣu yii.

“Ti ẹ ba kan fi owo ku owo oṣu awọn oṣiṣẹ lia wa ojutu si ọrọ aje to mẹhẹ da bi pe wọn ko se nkankan.”