You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Mọ̀ síi nípa bí ìlànà ayẹyẹ ìfinijọba Charles III ṣe n lọ
Ọpọ eeyan kaakiri ilẹ Gẹesi ni wọn ti gbaradi lati se ayẹyẹ ifinijọba Charles III, eto ti o ko isin onigbagbọ ati ayẹyẹ faaji papọ.
Eto naa ti bẹrẹ ni Westminister Abbey lonii, ọjọ kẹfa, osu karun, ọdun 2023 nibi ti wọn a ti gbe Ade sori Ọba Charles ati iyawo rẹ Camila, awọn ni wọn o jẹ ori ade ogoji ile Gẹẹsi lati ọdun 1066.
Ayẹyẹ naa ni o ti n waye lati ẹgbẹrun ọdun sẹyin, bi eto naa yo se waye niyi lẹsẹẹsẹ.
Aago Mẹfa Owurọ
Ayẹyẹ naa ti bẹrẹ lati Buckingham Palace lọ si Westminister Abbey, ti wọn si faaye gba ero oluworan lati wọ bi Ọba ti n kọja lati aago mẹfa arọ.
Ibudo ti wọn yoo lo...
Awọn ero oluworan to ba kọkọ de si ibudo: The Mall ati Whitehall ni wọn o fun ni aaye lati wọle ki wọn to dari awọn ti o ba sẹku si Hyde Park, Green Park ati St James’s Park ti awọn agbegbe yi ba ti kun.
Wọn o pese aaye ti awọn alejo ti wọn fiwe pe maa duro si, pẹlu awọn ọmọ ogun to ti fẹyin ti awọn osisẹ ile iwosan ati awọn osisẹ ilu mi ni ita aafin Buckingham.
Ọmọ isẹ ologun to din ni igba -ọpọ wọn wa lati ẹka Olominira to wa ninu aafin ni yoo kopa ninu eto lilọ si Westminister Abbey ti wọn o si ti kora jọpọ laaro ọjọ Satide.
Ẹgbẹrun awọn osisẹ ologun yoo to si ẹba ọna ti wọn o gba, apapọ awọn ti yo kopa ninu ayẹyẹ yi a kere si ti awọn to kopa nibi irufẹ ayẹyẹ ọhun ni ọdun 1953 nigba ti awọn idilẹ Ọba ati awọn olori ajọ Commonwealth kopa ninu ayẹyẹ naa.
10:20 aarọ : Ayẹyẹ bẹrẹ
Ayẹyẹ ifinijọba a bẹrẹ lati Aafin Buckingham laago mẹwaa kọja iṣẹju ogun, lo si agbegbe The Mall si Trafalgar Square si Whitehall si opopona Parliament ki wọn to yipo lo si Parliament Square ati Braod Sanctuary titi wọn o fi de Great West Door ti Westminister Abbey.
Ọba Charles ati Iyawo rẹ Camilla a wọ kẹkẹ Diamond Jubilee dipo kẹkẹ Gold State ti o ni aaye to fẹẹ daradara.
Wiwọ Westminister Abbey :
Ikọwọ rin Ọba Charles yoo de si Westminister Abbey ki aago mọkanla to lu,
O seese ki Ọba wọ asọ Ologun rẹ dipo asọ isẹnbaye ti awọn Ọba isaaju maa n wọ.
11:00 Kini yóò ṣẹlẹ̀?
Ọba Charles yoo gba Great West Door wọle titi yoo fi de aarin gbungbun gbangan Westminister Abbey.
Ipa wo ni àjó agbaye Commonwealth a kó nibi iwuye?
Awọn adari ẹsin ati asoju awọn orilẹede labẹ ajọ Commonwealth yoo duro niwaju Ọba ti wọn o si mu asia orilẹede wọn lọwọ, pẹlu awọn gomina ati olori Ijọba yo pẹlu wọn.
Olori ilẹ Gẹẹsi, Rishi Sunak a fi iwe ti wọn a ka sọwọ ninu isin naa.
Ayẹyẹ ọhun yoo bẹrẹ laago mọkanla, orin ti Ọba ba yan ni wọn o maa kọ pẹlu asayan orin mejila miran pelu orin Andrew Lloyd Webber pelu orin isẹmbaye awọn Giriiki ni iranti baba Ọba ,Philip.
Ọmọ ọmọ ọmọba, George yoo kọwọrin pẹlu awọn ti yoo wo gbọngan Westminister Abbey pẹlu awọn ọmọ ọmọ Camila, Lola, Eliza, Gus, Louis ati Freddy.
Wọn o wa lara awọn ti yoo gbẹ awọn eroja ti wọn a lo ninu Westminister Abbey lọwọ ninu asọ alaranbara.
Lara ohun eelo ti wọn o fun Ọba Charles ni Soverighn Orb, Ọpa asẹ to ni agbelebu lori ati ọpa asẹ to ni aworan ẹyẹ adaba lori.
Ti wọn o si tun fun iyawo Ọba Charles pẹlu ni ọpa asẹ olori to ni aworan ẹyẹ adaba ati ẹya agbelebu ,
o fẹ farapẹ irufẹ eyi ti wọn fun Ọba Chales, ayẹyẹ yii yoo to wakati meji .
Wọn o kede rẹ bi Ọba
Wọn o fi han gẹgẹ bi Ọba niwaju awọn eeyan, ayẹyẹ yi lo ti wa igba pipẹ, yoo duro lẹgbẹ aga ifinijọba ti yoo si yipo si igun mẹrẹẹrin inu gbọngan ọhun ti gbogbo eeyan o si kede rẹ bi Ọba.
Alufa ijọ Canterbury, Justin Welby ni yoo kọkọ kẹdẹ rẹ fun igba akọkọ.
Arabinrin Garter ati Thistle yoo kede rẹ sikeji, awọn ni wọn soju eeyan to dagba julọ ni England ati Scotland, ti gbogbo apejọpọ yoo kede wi pe ki Olorun gba Ọba pẹlu iro feere.
Wo aga itẹ Oba:
Aga ti wọn n lo fun iwuye ni wọn n pe ni aga St Edward,
ohun ni aga to dagba julọ nilu Ọba ti wọn n ṣii n lo fun oye Ọba jijẹ,
apapọ Ọba mẹrindinlọgbọn ni wọn ti fi bura fun bayii.
Ọba ile Gẹesi Edward I lo ti kọkọ pasẹ ki wọn fi okuta kadara sara aga naa.
Lodun 1996 wọn da okuta naa pada si orilẹede Scotland nibi ti wọn ti mu okuta naa wa,
sugbon ti Scotland da a pada fun nilo ninu eto ifinijoye yii.
IBURA:
Ṣaaju ibura, adari ijọ Canterbury yoo kede gbogbo ẹsin ti wọn n sin ni ilẹ Gẹẹsi ti yoo si pe fun ibara ẹni lopọ laarin awọn ẹlẹsin naa.
Adari ijọ Canterbury yoo ka ilana ibura fun Ọba Charles, ibura yii pọn dandan,
yoo bura lati pa ofin ati ofin ati ijọ ilẹ Gẹẹsi mọ nigba to wa lori oye.
Ọba yoo gbe ọwọ rẹ sori Bibeli ti yoo si seleri lati pa ibura naa mọ
Ifami-ororo-yan.
Wọn o bọ asọ iwuye Ọba Charles ti yoo si joko ninu aga ifinijọba ti wọn o si da ororo iwuye le e lori lati samin agbelebu si iwaju ori rẹ, lati fihan wi pe oun ni olori ijọ ilẹ Gẹẹsi.
Adari ijọ yoo da ororo naa le lori lati inu Ampulla sinu ibi ti wọn o si da a si lori, aya ati ọwọ.
Ampulla lo dabi aworan ẹyẹ to ni awọ goolu .
Gbigba ade:
Igba yii ni Ọba Charles yoo de ade St Edwars fun igba akọkọ laye rẹ,
wọn se ade naa fun Ọba Charles II ẹni ti o fẹ irufẹ ade ti Edward akọkọ de sori to si tun lẹwa ju ti akọkọ lo.
Ọba Charles III ni yo jẹ Ọba keje lẹyin Charles II, James II, William III,George VI ati Elizabeth II ti o wọ ọ kẹyin nigba ayẹyẹ ifinijọba ọdun 1953.
Ọba Charles yoo wo asọ ti wọn n pe ni Supertunica, pẹlu awọn ọpa asẹ.
Adari ijọ yoo gbe ade St Edward sori Ọba ti aago inu Westminister Abbey yoo dun fun isẹju meji, fere yoo tẹle ti wọn o si yinbọn soke jake jado ilẹ gẹẹsi
Gbigbe sori aga Ọba :
Eyi ni abala to kẹyin ninu ayẹyẹ ifinijọba nibiti awọn olori ijọ Canterbury yoo ti gbe Ọba tuntun lọ si ori aga ọba,
gẹgẹ bi asa, awọn to lẹtọ si jijẹ ọba yoo lo ki Ọba tuntun sugbọn lakoko yii, ọmọ ọba Charles nikan ni yoo lo ki oba tuntun.
Adari ijọ yoo si ke pe gbogbo awọn to wa ninu gbọngan Abbey ati awọn to n woran lati ile ki wọn fori balẹ fun Ọba tuntun.
Ọba ati iyawo rẹ yoo wo gbọngan St Edwards to wa lẹyin pipẹ giga, nibi ni yoo ti bọ ade St Edward ti yoo si wọ ade Imperial State ko to darapọ mo awọn to n jade ninu Abbey bi wọn ti n kọrin ilu Gẹesi.
Ọna ti wọn o gba lati Westminister Abbey si aafin Buckingham lo to maili meji din die,Ọba Charles ati iyawo rẹ ikinni ologun lọwọ awọn osiṣẹ ologun.
Latia ọdun 1953, ọna ti wọn o gba le ni mili mẹrin ti yoo si gba a to isẹju marundinladọta ki gbogbo eto naa to kọja awọn ibi ti wọn la kalẹ.