You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Wọ́n fẹ́ fi ìgbálẹ̀ àti pankẹ́rẹ́ lé mi kúrò láàfin torí Adeleke, Ọlọrun ló yọ mí – Ataoja Osogbo
Osun Election: Ataoja ni yóò tún fa gómìnà míì kalẹ̀ lẹ́yìn ọdún mẹ́jọ Adeleke nípò gómìnà
Ataoja ti ilu Osogbo, Oba Jimoh Oyetunji, ti ki gomina ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan nipinlẹ Osun, Ademola Adeleke ku oriire.
Ọba Oyetunji, ninu fidio kan to lu ori ayelujara pa, lasiko to n ki Adeleke nigba ti gomina tuntun naa ṣabẹwo si aafin rẹ sọ pe, awọn eeyan kan dunkoko mọ oun pe awọn yoo fi pankẹrẹ le oun kuro ninu afin amọ Ọlọrun lo ko oun yọ.
Ti ẹ ko ba gbagbe, Adeleke ti kọkọ bẹ aafin Ataoja wo, nibi ti ọba alade naa ti gbe awọn jaduku kan to kọlu awọn alatilẹyin ẹgbẹ PDP ṣepe ninu aafin ọhun.
Igbesẹ ti Ataoja gbe naa ko tẹ awọn araalu kan lọrun, eyii to mu ki wọn fẹsun kan ori ade ọhun pe o n ṣatilẹyin fun ẹgbẹ oṣelu kan ju awọn miran lọ.
Wọn fẹ fi igbalẹ ati pankẹrẹ le mi kuro laafin, Ọlọrun lo yọ mi
Amọ nigba ti Ataoja n sọrọ lasiko ti Adeleke de ba a lalejo lẹyin to jawe olubori ninu idibo gomina tan, o ni kii ṣe Adeleke nikan lo ṣe oriire, nitori oun naa ṣe oriire lẹyin idibo naa.
O sọ pe awọn eeyan kan ko ba ti fi pankẹrẹ le oun danu kuro laafin.
Ataoja ni “Mo ki gbogbo awa ti Ọlọrun yan gomina tuntun fun pe a ku oriire o, Ọlọrun yoo jẹ ki oriire naa o kalẹ.”
Èmi ni màá tún fa gómìnà míì kalẹ̀ lẹ́yìn tí Adeleke bá ṣe ọdún mẹ́jọ:
“Ẹ jẹ ki wọn mọ pe ayọ mi ti de... ki wọn maa sọ pe awọn yoo fi igbalẹ gba mi bọ sita ninu aafin pẹlu pankẹrẹ.”
“Ọlọrun lo yọ mi, kii ṣe Ademola nikan lo ṣoriire, Ataoja Jimoh naa ṣe oriire.”
“Ki eku ile o gbọ, ko sọ fun t’oko, kii ṣe emi ni ẹ o fi pankẹrẹ le.”
Ataoja pari ọrọ rẹ pe lagbara Ọlọrun, ti Adeleke ba pari saa rẹ tan, yoo ṣe ọdun mẹrin mii si, ti yoo fi pe ọdun mẹjọ lori oye.
O wa fikun pe lẹyin naa ni oun yoo tun kede ẹlomiran ti yoo di gomina ipinlẹ Osun.