Ìjọba Oyo fi ẹ̀ṣọ́ aláàbò sọwọ́ sí Ipapo/Iseyin lẹ́yin tí wọ́n jí àwọn àgbẹ̀ gbe lópin ọ̀sẹ̀

Ijọba ipinlẹ Oyo ti fi awọn agbofinro ṣọwọ si agbegbe Ipapo/Iseyin ni iha Ariwa ipinlẹ naa lati daabo bo awọn eeyan to n gbe nibẹ.

Igbesẹ ọhun ko ṣẹyin bi awọn ajinigbe tun ṣe ṣọṣẹ nibẹ lọjọ Abamẹta, ninu eyii ti wọn ti ji awọn agbẹ kan gbe lọ.

Ijọba ipinlẹ naa ti parọwa si awọn eeyan agbegbe Ipapo ki wọn fi ọkan wọn balẹ lẹyin iṣẹlẹ ijinigbe naa nitori oun yoo daabo bo wọn.

Ninu atẹjade kan ti kọmiṣọna fun iroyin ati aṣa, Wasiu Olatubosun fi lede, o ni kọmiṣọna fun eto ọgbin, Adeniyi Adebisi ti fi to oun leti pe wọn ti dari awọn ọlọpaa atawọn ọmọ ogun si agbegbe naa.

O ni ijọba ipinlẹ Oyo ko fi abo ẹmi ati dukia awọn eeyan ipinlẹ naa ṣere rara, paapaa awọn agbẹ.

Olatubosun ni “Ijọba ti ṣetan lati ṣawari awọn eeyan ti wọn ji gbew, ati lati da wọn pada sọdọ awọn ẹbi wọn layọ ati alaafia.”

“A n reti ki awọn ọmọ ogun darapọ mọ awọn ẹṣọ alaabo to wa nibẹ, kii ṣe lati ṣawari awọn eeyan ti wọn ji gbe nikan, amọ lati tun rii daju pe irufẹ iṣẹlẹ bẹẹ ko waye mọ.”

“Fun idi eyii, a ti ke si gbogbo awọn ẹṣọ alaabo, to fi mọ awọn ọmọ ogun lati bẹrẹ si n tọpinpin awọn ọdaran naa.”

Lẹyin naa lo ni iṣẹ ti n lọ lọwọ lati ri daju irufẹ iṣẹlẹ bẹẹ di ohun igbagbe nipinlẹ Oyo.