You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Irọ́ lo pa! Ariwo Yorùbá Nation rẹ̀, ọgbọ́n àti dá ọmọ Yorùbá sínú láàsìgbò ni - Tinubu fún Akintoye lésì
Ikọ̀ ìpolongo ipò Ààrẹ Tinubu/Shettima ti fún Ọ̀jọ̀gbọ́n Banji Akintoye lésì lórí àtẹ̀jáde tí ó fi síta wí pé àwọn kò ṣe àtìlẹyìn fún ìdíje Tinubu láti dupò Ààrẹ Nàìjíríà.
Nínú àtẹ̀jáde kan tí agbẹnusọ ikọ̀ ìpolongo náà, Bayo Onanuga fi síta ní ọ̀rọ̀ ara Banji Akintoye ló ń sọ kìí ṣe wí pé ó ń gba ẹnu gbogbo ọmọ Yorùbá sọ̀rọ̀.
Onanuga ní irọ́ lásán ni gbogbo ìdúnkokò tí Akintoye ń dún wí pé ẹ̀yà Yorùbá ń gbèrò láti ya kúrò lára Nàìjíríà nítorí kò sí ìjókòó kankan tó wáyé níbi tí àwọn Yorùbá ti ní àwọn ti ṣetán láti kúrò.
“Kò sí ibi kankan tí àpapọ̀ ọmọ Yorùbá ti jókòó tí wọ́n wá yan Ọ̀jọ̀gbọ́n Banji Akintoye àti ikọ̀ rẹ̀ láti ṣe ìdásílẹ̀ Ilana Yoruba láti fi gba ìran Yorùbá kúrò lára orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.”
Ó ní gbogbo ìgbìyànjú Akintoye láti da àwọn ọmọ Yorùbá sínú làásìgbò tàbí jẹ́ kí irúfẹ́ ohun tó wáyé ní Rwanda wáyé ní Nàìjíríà ni kò ní wá sí ìmúṣẹ.
Tinubu kò dupò ààrẹ nítorí ìmọtaraẹni nìkan
Nígbà tó ń lórí ẹ̀sùn tí Banji Akintoye fi kan Tinubu wí pé kò ní àǹfàní kankan tí yóò ṣe fún Nàìjíríà lórí ipò ààrẹ tó ń wá, Onanuga ní gbogbo ẹnu ni òun fi sọ wí pé Asiwaju Bola Tinubu ní ìfarajìn sí iṣẹ́ ìsìn ọmọnìyàn ló ṣe gbégbá láti di Ààrẹ Nàìjíríà.
Ó ní ìgbàgbọ́ Tinubu nínú ìṣọ̀kan àti ìdúróire Nàìjíríà níbi tí gbogbo ènìyàn orílẹ̀ èdè yìí yóò ti jẹ múkùndún ìjọba àwaarawa láìfi ẹ̀yà tàbí ẹ̀sìn ṣe ló ṣe gbégbá láti di ààrẹ.
Ó fi kun pé gbogbo àwọn ohun tí Ọjọgbọn Akintoye sọ wí pé ó jẹ àwọn lógún ni Tinubu ti ṣaájú sọ wí pé òun yóò gbájúmọ́ tí òun bá di ààrẹ Nàìjíríà nígbà tó ń ṣàfilọ́lẹ̀ àwọn nǹkan tó fẹ́ ṣe tó bá di ààrẹ.
Onanuga tẹ̀síwájú pé Tinubu mọ̀ wí pé agbára tó sodo sọ́wọ́ ìjọba àpapọ̀ ti pọ̀ púpọ̀ jù ló fàá tí àwọn ìpínlẹ̀ kò fi gòkè tó bó ṣe yẹ tó sì ṣèlérí láti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin láti fi ààyè gba àwọn ìjọba ìbílẹ̀ láti le wà ní ààyè ara wọn ju bí wọ́n ṣe wà lásìkò yìí lọ.
Ó ní ó jẹ́ ohun ìyàlẹ́nu fún àwọn wí pé Ọ̀jọ̀gbọ́n Banji Akintoye tó ti fìgbà kan rí jẹ́ sẹ́nétọ̀ ní Nàìjíríà ló yẹ kó jẹ́ atọ́nà fún àwọn ọ̀dọ́ tó ń bọ̀ lẹ́yìn dípò ṣíṣi àwọn ènìyàn lọ́nà.
Bákan náà ló ní ikọ̀ ìpolongo Tinubu kò lo fídíò Banji Akintoye kankan láti fi ṣe ìpolongo ìbò fún Tinubu tàbí ẹnikẹ́ni.
Oró làwọn ọmọ Yoruba tó ń díje ní ìbò 2023 ń dá àwọn ẹbí wọn
Ẹ o ranti pe a mu iroyin wa fun-un yin pe ẹgbẹ to n ja fun idasilẹ orilẹede ẹya Yoruba, Ilana Ọmọ Oodua ti sọ pe oro nla lawọn ọmọ ilẹ Yoruba gbogbo to ba kopa ninu eto idibo 2023 lorilẹede Naijiria n da fun awon mọlẹbi wọn.
Adari apapọ ẹgbẹ Ilana ọmọ Oodua, Ọjọgbọn Banji Akintoye to sọ eyi ninu atẹjade kan to fi sita sọ pe bi orilẹede Naijiria ṣe wa bayi, ko si anfani kankan ti ẹya Yoruba lee ri jẹ lara rẹ. O ni oniruuru ifasẹyin ni apapọ orilẹede Naijiria ti mu ba oniruuru igbesẹ idagbasoke bii ẹkọ ofe, igbayegbadun araalu, ilera ọfẹ ati bẹẹbẹ lọ ti awọn Akin ọmọ Yoruba ti gbe kalẹ fun ẹya Yoruba.
Bakan naa lo fi kun un pe nṣe lawọn ọmọ Yoruba to n dije, paapaa Aṣiwaju Ahmed Bola Tinubu to n dije fun ipo aarẹ Naijiria lẹgbẹ oṣelu APC n ba ọjọ iwaju Yoruba jẹ ati pe ogun ti yoo mu itinu ba atiranderan lo nle.
Adari ẹgbẹ Yoruba naa ṣalaye pe oun ko si lẹyin eyikeyi awọn ọmọ Yoruba to n dije fun ipo oṣelu gbogbo lọdun 2023, ṣugbọn ohun wa lẹyin awọn ọdọ to n lepa ati gba orilẹede wọn pada lọwọ awọn adari to n ṣe ṣuta fún wọn.
Ọjọgbọn Akintoye ni lootọ loun ti fi igba kan ri kan sara si Tinubu gẹgẹ bi ẹni to kun oju oṣuwọn lati dari Naijiria nigba kan ri ti ina ko tii jo de ori koko ṣugbọn iṣẹlẹ lọwọlọwọ yii fun Yoruba lorilẹede Naijiria fihan pe nnkan ti yi pada.
O ni ohun to bani ninujẹ pupọ ni lati ri ilẹ Yoruba to n lewaju pẹlu awọn ohun amayedẹrun ni Afrika wa di eyi ti gbogbo ohun elo amayedẹrun rẹ wa dẹnukọlẹ.
“Awọn opopona ijọba apapọ n ba ọrọ aje ẹkun wa jẹ. Fasiti wa ni ilu Ifẹ ti ṣe kẹrẹkẹrẹ di ẹgẹrẹmiti. A ko lee kọ ẹkọ imọ nipa ita wa mọ lawọn ile ẹkọ. A ko le kọ ede wa mọ lawọn ile ẹkọ wa gbogbo. A ti di ẹru ni Naijiria. A ko si lee maa ba bayi lọ.”