You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
N5mílíọ̀nù ni Chidinma wọ́ kúrò ní àsùwọ̀n owó Usifo Ataga lọ́jọ́ tó kú – Óṣojúmikòró
Chidinma Ojukwu to jẹ olori afurasi ninu iṣẹlẹ iku ọga ileeṣẹ Tẹlifisan Super TV, Usifo Ataga ji owo miliọnu marun kuro ninu apo asuwọn owo oloogbe naa ni ọjọ ti wọn fẹsun kan pe o pa a.
Eyi ni ohun ti ọkan lara awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn sọ nibi igbẹjọ to waye ni Ọjọbọ ọsẹ nile ẹjọ giga ilu Eko.
Eeyan to to wa jẹri naa, DSP Bamidele sọ pe Chidinma tun wọ ọpọlọpọ owo mii latinu asuwọn owo Ataga to wa ni Banki Access ati GTB.
Nigba ti wọn wo akọsilẹ rẹ lawọn Banki mejeji, to si fi wn han nile ẹjọ, o fikun un pe bi awọn ṣe n ṣe iwadii lawọn ke si awọn banki ọhun pe ki wọn fi akọsilẹ owo rẹ ranṣẹ.
Nigba ti wọn fi wo iwe akọsilẹ naa, wọn rii pe lati ọjọ Kẹrindinlogun titi di ọjọ Kọ̀kandinlogun oṣu Kẹfa ni afurasi Chidinma ti bẹrẹ si ni ṣe akoso asuwọn owo oloogbe Ataga. O ti n fi ra data sori foonu rẹ nitori o da bii pe oun lo mu foonu arakunrin naa dani.
O ti gba iye owo N20,026.88 nigba mẹta ni ọjọ Kẹrindinlogun, nigba to tun di ọjọ Kẹtadinlogun o gba N20,026.88 nigba marun.
Ni ọjọ Kejidinlogun, o gba N110,000 ati nigba to ya,o tun gba N20,026.88 nigba mẹrin. Lọjọ Kọkandinlogun, o gba N20,026.88 nigba marun.
Akọroyin BBC jabọ gẹlẹ bo ṣe gbọ ọ nile ẹjọ pe nipasẹ USSD lo fi gba awọn owo yii lori foonu oloogbe, o sọ bẹẹ funra rẹ.
O ti tẹsiwaju ninu Akọsilẹ oloogbe pe ni ọjọ Kẹẹdogun gan lo wọ miliọnu marun Nairia latinu asuwọn owo Ataga sinu asuwọn owo mii.
DSP Bamidele tun sọ pe ọpọlọpọ owo lo gba latinu asuwọn owo GTB sinu awọn asuwọn owo mii ati ileeṣẹ kaakiri.
Bakan naa ni ẹni to jẹri yii gbe awọn iwe akọsilẹ ọhun fun awọn agbẹjọro afurasi gẹgẹ bi ẹri.
Ẹwẹ, agbẹjọro afurasi, Onwuka Egwu pe akọsilẹ naa nija wipe awọn alaṣẹ gba awọn akọsilẹ naa nipasẹ ipa ati nini eeyan lara.
O wa ni ki ile ẹjọ ṣe agbekalẹ ilana ti wọn lee lo fi ṣagbeyẹwo bi akọsilẹ naa ṣe jẹ gangan.
Adajọ agba gba awọn akọsilẹ naa gẹgẹ bi ẹri keji ati ikẹta. Adajọ Yetunde Adesanya wa sun igbẹjọ naa siwaju di ọjọ Kẹjọ Oṣu Kẹrinla.
Latigba ti wọn ti fi ofin mu afurasi yii ni ile ẹjọ ti pe eeyan mẹsan ọtọọtọ lati wa jẹri.