You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Dọ́là làwọn ajínigbé yóò má bèèrè, bí CBN bá pàárọ̀ náírà sí tuntun - Gumi
Sheik Gumi ní ìṣẹ́ àti òṣì yóò túbọ̀ pọ̀ sí láàrin àwọn mẹ̀kúnnù bíjọba bá ní ká máà ná ike bíi owó díbò bébà
Onimọ nipa ẹsin Islam kan to tun gbajumọ nitrori ifarakinra rẹ pẹlu awọn ajinigbe, Sheik Ahmad Gumi, ti sọrọ lori erongba banki apapọ ilẹ wa lati paarọ beba naira ilẹ wa si tuntun.
Ninu atẹjade kan ti Gumi fisita lori igbesẹ naa lo ti safihan awọn erongba rẹ ọhun.
Gumi ni ti banki CBN ba fi paarọ owo beba Naira si tuntun, isẹ ati osi to n bawọn ọmọ Naijiria finra yoo tubọ pọ si.
O fikun pe awọn aijare ti CBN n wi lati paarọ owo beba Naira si tuntun naa, yoo tubọ ti awọn agbebọn lati maa bẹrẹ si ni beere owo Dọla lọwọ awọn eeyan ti wọn ba ji gbe dipo Naira.
“Emi, gẹgẹ bi onimọ nipa ẹsin Islam woye pe ilana pasipaarọ owo Naira si beba tuntun tako ifẹ araalu.
Bakan naa ni igbesẹ naa fẹ waye lakoko ti ko yẹ rara, paapaa lati ọdọ ijọba to n palẹmọ lati kogba wọle.
"Owo Naira tuntun le se agbende wahala ọrọ aje ati awujọ ni Naijiria"
Igbesẹ yii yoo tumọ se afikun iya to n jẹ awọn mẹkunnu ni nitori ọpọ kii lọ sile ifowopamọ lati gba owo gẹgẹ bii awọn ọlọ́rọ̀.
Koda, igbesẹ naa yoo tubọ jẹ ki awọn agbebọn maa beere fun owo Dọla lọ́wọ awọn ti wọn ba ji gbe gẹgẹ bii owo idande ni.”
Gumi fikun pe ida ọgọrin ninu ọgọrun awọn ọmọ Naijiria, paapaa awọn eeyan to wa ni agbegbe igberiko lo n na owo beba ju ike-owo lọ.
O ni ayipada pajawiri si ilana lilo ike lori ayelujara lati nawo yii yatọ si owo beba tawọn mẹkunnu n na, yoo tubọ sọ isẹ ati osi di pupọ ni.
O ni igbesẹ naa tun le se agbende wahala ọrọ aje ati awujọ yii, ti ọpọ ọmọ orilẹede yii ko si ni isẹ ọwọ kankan tabi ko ni aabọ isẹ ọwọ.
A ti gba àṣe lọ́wọ́ Ààrẹ Muhammadu Buhari kí a tó gbé ìgbésẹ̀ lórí owó naira tuntun – CBN
Banki apapọ Naijiria, CBN, ti sọ pe oun tẹle gbogbo ilana to yẹ lati tẹ igba naira, ẹẹdẹgbẹta naira ati ẹgbẹrun naira tuntun.
Agbẹnusọ CBN, Osita Nwanisobi lo sọ ọrọ naa lasiko to n fesi si ọrọ ti minisita fun eto iṣuna lorilẹede, Zainab Ahmed sọ pe CBN ko fi ọrọ lọ ileeṣẹ eto iṣuna ijọba apapọ ko to gbe igbesẹ pe oun yoo yi awọn owo Naijiria pada lọṣu kejila.
Nwanisobi sọ pe iyalẹnu lo jẹ fun oun nipa ohun ti minisita naa sọ nitori CBN jẹ banki to maa n tẹle ilana to yẹ ki wọn to ṣe ohunkohun.
Gẹgẹ bii ohun ti Nwanisobi sọ, awọn alaṣẹ CBN ti gba aṣẹ lati ọdọ Aarẹ Muhammadu Buhari ki wọn to bẹrẹ igbesẹ lati tẹ owo tuntun bo ṣe wa ninu abala keji, abala kejidinlogun ati abala kọkandinlogun ofin to to rọ mọ iṣẹ CBN ti ọdun 2007.
O ni CBN ti koju awọn ipanija kan, eyii to le ṣe ipalara fun owo Naijiria, CBN funra rẹ ati orilẹ-ede Naijiria lapapọ.
O fikun un pe banki awọn ti ṣetan lati ṣe ohun gbogbo to yẹ lati daabo bo owo naira, ati ọna ti owo naa yoo ṣe tẹ awọn araalu lọwọ.
Nipa atunṣe ti wọn n ṣe si owo naira lọwọ, Nwanisobi ṣalaye pe ogun ọdun gbako ni CBN fi duro ko to bẹrẹ igbesẹ lati tẹ owo tuntun.
Ọjọru to kọja yii ni gomina CBN, Godwin Emefiele sọ pe awọn yoo tẹ owo tuntun mii lati ori igba, ẹẹdeẹgbẹta to ẹgbẹrun kan naira lati ọjọ karundinlogun, oṣu Kẹjila, ọdun 2022 yii.
Emefiele fi kun un pe awọn araalu ṣi le maa na awọn owo to ṣi wa ni nita titi di ọjọ kọkanleọgbọn, oṣu Kinni, ọdun 2023 ti wọn yoo ko kuro nilẹ patapata.
Ki lo ti ṣẹlẹ sẹyin?
CBN kò fi ìgbésẹ̀ àyípadà Naira tó iléeṣẹ́ ètò ìṣúná létí -Zainab Ahmed
Minisita fun eto iṣuna lorilẹede Naijiria, Zainab Ahmed ti sọ pe banki apapọ Naijiria, ko fi ọrọ lọ ileeṣẹ eto iṣuna ijọba apapọ ko to gbe igbesẹ pe oun yoo yi awọn owo Naijiria pada lọṣu kejila.
Lasiko to fi n dahun ibeere niwaju igbimọ tẹẹkoto lori iṣuna nile aṣofin agba Naijiria, lori iṣuna ileeṣẹ rẹ fun ọdun 2023 gẹgẹbi akọsilẹ iwe iṣuna apapọ Naijiria ti aarẹ Muhammadu Buhari gbe ka iwaju ile aṣofin apapọ, lo ti sọ eyi.
Minisita Zainab ni lootọ lara awọn idi ti banki apapọ Naijiria gbe kalẹ fun igbesẹ naa ni lati wa nnkan ṣe si ọwọngogo to gbode, amọ sibẹ o ni yoo lẹyin.
“Wọn ko fi to wa leti, ikede ni awa naa gbọ. Lara idi ti wọn kede fun igbesẹ naa ni lati palẹmọ awọn owo to n lọ kaakiri ni igboro lati lee wojutu si iṣoro ọwọngogo.
“Amọṣa atunbọtan yoo tun wa fun un pẹlu -a n gbiyanju ati wo awọn ohun ti atunbọtan yii yoo jẹ. Bakan naa ni ire yoo ti ẹyin rẹ yọ o, ṣugbọn ipenija yoo wa pẹlu.
“Amọṣa mi o wa mọ o boya awọn alaṣẹ banki naa ti boju wo awọn ipenija to lee suyọ ati ọna lati bu omi paa.”
Ki ni ile aṣofin agba Naijiria sọ sii?
Sẹnetọ Michael Ọpẹyẹmi Bamidele ṣalaye lasiko ijoko naa pe ko tii pe ọjọ meji lẹyin ti Banki apapọ Naijiria kede igbesẹ ayipada owo Naijiria naa ti iye ti wọn n ṣe paṣiparọ owo Naira si Dla ilẹ Amẹrika ti gbẹnusoke kuro ni ojilelẹẹdẹgbẹrin naira (N740) si Dọla kan lọ si Ọrinlelẹẹdẹgbẹrin o le mẹjọ naira (N788) si dọla kan pẹlu bi awọn eeyan ṣe n jijadu lati yi gbogbo owo Nairia ti wọn ko pamọ sile pada si owo ilẹ okeere, paapaajulọ owo Dọ̀la ilẹ Amẹrika.
“Fun emi o, lootọ o le jẹ erongba rere lo mu igbesẹ yii wa, ṣugbọn asiko ti wọn gbe e si yii, pẹlu ohun gbogbo to wa nilẹ bayii, asiko ti ko tọna gba a ni. Afaimọ ki owo naira maadẹnukọlẹ si dọla pẹlu bii ẹgbẹrun kan naira si dọla kan nigba ti igbesẹ naa yoo ba fi gbinaya loṣu kini ọdun 2023.”
Banki apapọ Naijiria, CBN kede igbesẹ ati yi owo Naijiria pada
Ni Ọjọru ni Banki apapọ Naijiria kede pe oun yoo bẹrẹ si nii pin owo naira tuntun bẹrẹ lati ọjọ karundinlogun oṣu kejila ọdun 2022.
Labẹ eto yii beba owo naira - ọgọrun naira N100, igba naira N200, ẹẹdẹgbẹta Naira N500 ati ẹgbẹrun kan Naira, N1000 yoo gbe awọ tuntun wọ.
Gomina agba banki apapọ Naijiria, Godwin Emefiele sọ pe igbesẹ yii wa lati wojutu si iwa ipese iṣuna fun igbesunmọmi, kiko owo pamọ sile.
Emefiele niida marundinlaadọrun owo to n tọwọdọwọ ni Naijiria lo jẹ wi pe owo ti ko ti aṣuwọn awọn banki jade ni wọn jẹ.
EFCC gbé òṣùbà káre fún CBN lórí ìpinnu láti mú ìyípadà bá owó Naira
Ajọ to n gbogun ti iwa ajẹbanu lorileede Naijiria EFCC sọ pe rẹgi ni igbesẹ ti ijọba Naijiria gbe lati mu iyipada ba owo Naira ṣe lọkan awọn.
Alaga ajọ naa Abdulrasheed Bawa lo fidi ọrọ yi mulẹ ninu esi to fọ loju opo ajọ naa lori Twitter.
O ni igbesẹ yi ṣe deede gẹgẹ bi ''idahun si awọn ipenija to n koju iṣakoso owo Naira ni Naijiria eyi to ti ni ipa lori ọrọ aje ati aabo to peye''
O fi kun pe EFCC, CBN ati awọn alẹnulọrọ miran ti n ṣiṣẹ papọ latẹyinwa lọna ati mu iduro deede ba ẹka owo Naijiria.
Abdulrasheed Bawa sọ pe ọkan akin ni CBN gbe pẹlu igbesẹ yi ti oun si ni igbagbọ pe yoo mu iyipada rere ba iṣakoso owo Naira lorileede Naijiria.
Yatọ si ọga EFCC to gboṣuba kare fun CBN lori igbesẹ yi, awọn eekan ọmọ Naijiria mi naa ti n kan sara si CBN fun igbesẹ ati yi owo Naira pada.
Ninu wọn la ti ri Reno Omokri to jẹ alatako ijọba to si ni igbesẹ yi dẹkun awọn ajinigbe to n gba obitibiti owo lọwọ araalu ti wọn ba ji gbe.
Banki apapọ Naijiria ti kede pe oun yoo ṣe ifilọlẹ kaadi owo kan, One Card, bẹrẹ lati ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kinni, ọdun 2023.
CBN ṣe kaadi naa pẹlu ajọṣepọ awọn banki to wa ni Naijiria ati ajọ to n mojuto ibaṣepọ laarin awọn banki, NIBSS.
Ninu atẹjade kan to fi sita, agbẹnusọ fun CBN, Osita Nwanisobi sọ ninu awọn iwe iroyin pe kaadi tuntun naa yoo mu ki kata-kara rọrun, ti yoo si tun mu adinku ba owo ori ti awọn banki n gba lọwọ lọwọ awọn onibaara wọn.
Banki apapọ ni yatọ si pe kaadi tuntun naa yoo ran ẹka okoowo lọwọ nipa imọ ẹrọ, o ni yoo tun jẹ ọna abayọ si awọn iṣoro ti awọn banki ma n ni.
Pẹlu kaadi tuntun yii, araalu le fi san owo fun oriṣiriṣi ọja ati awọn nkan mii paapaa lori ayelujara ati ATM, dipo ki wọn o ma a lo ju kaadi ẹyọkan lọ.
CBN ṣalaye pe ti eto naa ba fi bẹrẹ, Naijiria yoo darapọ mọ awọn orilẹ-ede bii India, Turkey, China ati Brazil, to ti n lo kaadi owo kan ṣiṣo fun igba pipẹ.
CBN yóò kó owó N100,N200,N500 àti N1000 nílẹ̀ fún tuntun
Banki apapọ orileede Naijiria ti kede pe awọn ti ri aṣẹ gba lọdọ aarẹ Naijiria, Muhammadu Buhari lati gbe ẹda owo tuntun mii jade ni Naijiria.
Aṣẹ ti aarẹ fun wọn yi gẹgẹ bi Gomina Banki naa Godwin Emefiele ti ṣe wi,yoo ka owo ọgọrun,igba, ẹẹdẹgbẹta ati ẹgbẹrun Naira to wa nilẹ bayi.
Lasiko to n ba awọn akọroyin sọrọ ni ilu Abuja lo fidi ọrọ yi mulẹ.
Emefiele sọ pe aisi owo to tuntun nita jẹ nkan tawọn kọminu lori eleyi to mu ki iyipada ati ipese owo Naira mi ṣe pataki.
O ni lẹnu ọjọ mẹta yi, awọn ti n ri bawọn eeyan ti ṣe n ṣe ayederu owo Naira ni paapa owo ẹẹdẹgbẹta ati ẹgbẹrun Naira.
Nigba wo ni owo tuntun yoo jade?
Emefiele ṣalaye pe lati nkan bi ogun ọdun sẹyin ni iyipada ti de ba owo Naijiria kẹyin.
O ṣalaye pe lagbaye laarin ọdun marun un si ọdun mẹjọ lawọn ijọba maa n gbe owo tuntun jade.
O ni tori eyi ati awọn nkan mii to n lọ lode lo mu ki awọn fẹ parọ owo Naira to wa nita.
Amọ owo tuntun naa yoo bẹrẹ si ni tẹ awọn araalu lọwọ lati ọjọ Kẹẹdogun oṣu Kejila 2022.
Owo ti tẹlẹ nkọ?
Ninu alaye rẹ, o ni owo to wa nita yi yoo ṣi jẹ nina titi di ọjọ kọkanlelọgbọn oṣu Kini ọdun 2023.
O ni bi ọjọ yi ba ko, ẹni ti owo yi ba wa lọwọ rẹ ko ni ri owo ti tẹlẹ na mọ.
Torinaa Emefiele sọ pe awọn banki ko gbọdọ ja owo kankanlori alabara wọn to ba fẹ ko owo pamọ bẹrẹ lati wakati yi lọ.
O ni eleyi yoo fawọn eeyan lanfaani lati ko owo ọwọ wọn to jẹ ti tẹlẹ si ile ifowopamọ ṣaaju ki owo mii to jade.
Ipa tawọn banki ni lati ko ree
Emefiele fi kun alaye to ṣe pe awọn ile ikowopamọ si ni lati ṣe awọn nkan wọnyi ṣaaju ki owo tuntun to gbode:
- Awọn to ba kọkọ forukọ silẹ ni yoo ri owo tuntun naa gba
- Awọn banki gbọdọ ṣiṣẹ laarin ọjọ Aje si ọjọ Abamẹta ni paapa ẹka wọn ti yoo ma a gba owo ti tẹlẹ lọwọ araalu.