You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Wo àwọn gómìnà tó tí jẹ ní ìpínlẹ̀ Osun
Laarọ Aiku ni ajọ eleto idibo nilẹ wa kede esi idibo gomina nipinlẹ Osun to waye lọjọ Satide,.
Ẹni to bori eto idibo naa ni Sẹnatọ Ademola Adeleke tii se oludije fun ipo gomina labẹ asia ẹgbẹ oselu PDP.
Adeleke lo ni apapọ ibo 403,371 eyi to mu ko fi ẹyin gomina to wa lori aleefa janlẹ, eyiun Adegboyega Oyetola.
Eyi lo mu ki BBC yoruba ṣe akojọpọ awọn gomina ti o ti jẹ ni ipinlẹ Osun lati igba ti wọn ya kuro lati ipinlẹ Oyo atijọ lọdun 1991.
Leo Segun Ajiborisha
Ọdun 1992 ni Segun Ajiborisha , ọmọ ologun jẹ gomina akọkọ fun ipinlẹ Osun, ti o si wa lori aleefa lati ọdun 1991 si 1992.
Isiaka Adetunji Adeleke
Isiaka Adetunji Adeleke jẹ gomina awarawa akọkọ fun ipinlẹ Osun, oun si n ẹgbọn fun gomina tuntun bayi Ademola Adeleke. Adeleke bọ si ori aleefa pẹlu ẹgbẹ oṣelu SDP.
Ọdun 1992 si 1993 ni Isiaka Adeleke fi jẹ Gomina.
Gomina ologunAnthony Udofia, Anthony Obi ati Theophilus Bamigboye:
Ni kete ti ijọba ologun gba ijọba lọdun 1992, ijọba awarawa kogba wọle, ti awọn Ọmọ ologun si n se akoso.
Anthony Udofia, Anthony Obi ati Theophilus Bamigboye bọ ṣiṣẹ isakoso ipinlẹ Osun, ti wọn si ṣe ijọba lati ọdun 1993 si 1999.
Adebisi Akande:
Isẹ ijọba orilẹede Naijiria pada si ọwọ ijọba awarawa lọdun 1999, Adebisi Akande jade dije fun ipo aarẹ labe aisa ẹgbẹ oṣelu Action Democracy, ti bori etoo idibo lọdun naa
Adebisi Akande jẹ gomina keji labẹ akoso fun ijọba awarawa ni ipinlẹ Osun lati ọdun 1999 si ọdun 2003.
Olagunsoye Oyinlola:
Ọmọba Olagunsoye Oyinlola latinu ẹgbẹ oṣelu PDP gba isakoso ipinlẹ Osun lọwọ Gomina Adebisi Akande lọdun 2003.
Oyinlola jẹ gomina lati ọdun 2003 si ọdun 2010.
Rauf Aregbesola:
Rauf Aregbesola to wa lati ninu ẹgbẹ oselu Action Congress Nigeria (ACN) to ti parada di APC bayii, wa lara awọn oludije to jade dupo lọdun 2007.
Aregbesola lo mori le ile ẹjọ lẹyin ti Ajọ INEC kede Gomina Olagunsoye Oyinlola gẹgẹ bi gomina ipinlẹ naa fun saa keji
Nigbati o di ọdun 2010, ile ẹjọ gbe agbara fun Rauf Aregbesola pe oun lo jaweolubori ninu eti idibo ipinlẹ Osun lọdun 2007.
Ileẹjọ wa da Aregbesola lare, to si yẹ aga mọ Oyinlola nidii bii gomina.
Aregbesola wa jẹ gomina ipinlẹ lati ọdun 2010 di ọdun 2018 lẹyin ti o se saa meji lori aleefa.
Isiaka Gboyega Oyetola Isiaka Oyetola ni gomina lọwọlọwo bayi ni ipinlẹ Osun, ẹni to fi idi rẹmi ninu eto idibo ipinlẹ naa to waye lana si Ademola Adeleke
Oyetola lo gba isakoso lọwọ Rauf Aregbesola lọdun 2018 labẹ asia ẹgbẹ oṣelu All Progressive Congress APC.