You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
"Bàálù nìkan ni ajínigbé bẹ̀rù, ejò àti àkeekè yí wa ká, díẹ̀ ló kú káwọn ìkookò pa mí ní àhámọ́ ajínigbé"
Adarí tẹ́lẹ̀ fún àjọ àwọn àgùnbánirọ̀, Maharazu Tsiga ti ṣàlàyé àwọn nǹkan tí ó là kọjá ní àkàtà àwọn ajínigbé tó lo ọjọ́ mẹ́rìndínlọ́gọ́ta kó tó rí ìtúsílẹ̀.
Ó ní àwọn ìkokò yí òun àtàwọn mìíràn táwọn ajínigbé náà jí gbé ká ní ó ku ọjọ́ kan tí wọ́n tú òun sílẹ̀.
Ní ọjọ́ Karùn-ún, oṣù Kejì, ọdún 2025 ni wọ́n jí Tsiga ní ìlú rẹ̀, Tsiga ní ìjọba ìbílẹ̀ Bakori, ìpínlẹ̀ Katsina kó tó rí ìtúsílẹ̀ lọ́jọ́rú, ọjọ́ Kejì, oṣù Kẹta.
Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ ní ìlú Abuja lọ́jọ́bọ̀ lásìkò tí wọ́n ń kó àwọn mọ́kàndínlógún tí wọ́n gba ìtúsílẹ̀ ní àkàtà àwọn ajínigbé padà fáwọn ẹbí wọn, Tsiga ṣàlàyé gbogbo nǹkan tí ìṣòro tí wọ́n la kọjá.
"Nígbà tó ku ọjọ́ kan tí mà á kúrò níbẹ̀, ní orí òkè tí mo wà, a kàn déédé rí àwọn ìkoòkò tí wọ́n ń wá oúnjẹ káàkiri."
Ó fi kun pé àwọn tí wọ́n jí àwọn gbé máa ń ṣe alábàápàdé àwọn ejò àti àkeèkè nígbà tí àwọn ní àhámọ́ wọn.
Ó júwe báwọn ajínigbé náà ṣe ń lo àwọn èèkàn èèyàn lára àwọn tí wọ́n jí gbé, láti fi dá ààbò bo ara wọn lọ́wọ́ ìkọlù àwọn agbófinró tó ń wá wọn.
"Nígbà tí àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò bá ń fi ọkọ̀ òfurufú wá àwọn ajínigbé náà, wọ́n máa kó wa jáde láti jẹ́ pé àwa ni ohun tí wọ́n bá jù sí wa máa bà."
Ó sọ̀rọ̀ nípa bí àdó olóró tí wọ́n jù sí àárín wọn ṣùgbọ́n tí àdó olóró náà kọ̀ láti dún.
Tsiga fi kun pé, àwọn ajínigbé náà ní ìgbàgbọ́ pé àwọn tó bá ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ìjọba máa ń ní owó lọ́wọ́ àti pé èyí ló jẹ́ kí wọ́n já ilé òun pẹ̀lú àdó olóró láti jí òun gbé.
Ó sọ pé àwọn ajínigbé náà kò ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run àti pé nǹkan tí wọ́n bẹ̀rù kò kọjá tí wọ́n bá rí ọkọ̀ òfurufú tó ń fò lókè.
Tsiga ní ẹ̀ẹ̀kan lósẹ̀ péré ni àwọn ajínigbé náà máa ń fún àwọn lóúnjẹ Tuwo Dawa, tó sì jẹ́ pé òun ni yóò gbé àwọn fún ọ̀sẹ̀ kan.
Ó tẹmpẹlẹ mọ pé gbogbo èèyàn ni ọ̀rọ̀ ààbò orílẹ̀ èdè Nàìjíríà kàn, pé kí àwọn èèyàn yé fi ọ̀rọ̀ ààbò dá ìjọba nìkan nítorí gbogbo èèyàn ni ọ̀rọ̀ náà kàn.
Bákan náà ló rọ gbogbo àwọn aráàlù láti máa fi ìròyìn tó bá le ṣe ìrànwọ́ fáwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò létí.
Igbákejì tẹ́lẹ̀ rí fún eto isẹ ní Pretoria, South Africa, Gideon Yohan náà wà lára àwọn tó gba ìtúsílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ajínigbé náà.