Ẹ wo bí àwọn ará ilẹ̀ South Africa ṣe kí yìnyín káàbọ̀ lẹ́yìn ọdún mẹ́wàá tí wọn ò ríi

Awọn ara ilu Johannesburg to jẹ olu-ilu ilẹ South-Africa ni wọn ti ri yinyin tutu fun igba akọkọ lẹyin ọdun mẹwaa.

Nitori yinyin naa, Ijọba ti paṣẹ fun awọn araalu lati da abo bo ara wọn nipa wiwọ asọ otutu nitori nise ni oju ọjọ tutu kaakiri orilẹede naa.

Lasiko ti ileeṣẹ to n risi ọrọ oju ọjọ nibẹ ni yinyin naa ko ba nkankan jẹ, amọ o seese ki oju ọjọ tutu jọjọ fun gbogbo ọsẹ yii.

Iyalẹnu lo jẹ fun awọn ara ilu Johannesburg nigba ti yinyin gba gbogbo ode kan ni Ọjọ Aje nibẹ.

Lara awọn araalu to ba BBC sọrọ ni awọn akẹkọọ miran jade lati wo ohun to n ṣẹlẹ pẹlu iyalẹnu, nigba ti awọn miran si ro pe ojo lo n rọ.

‘’Awa ninu ile lati da abo bo ara wa ninu otutu yii, nise ni yinyin gba gbogbo ode kan, kaakiri gbogbo adugbo wa. O rẹwa lati ri daradara.’’

‘’Awọn agbegbe miran ti wọn tun ri yinyin ni agbegbe ila Eastern Cape, Mpumalanga, Gauteng to fi mo Soweto ni wọn ti ri yinyin yii.’’

Awọn onimọ nipa oju ọjọ ti gba awọn ileẹkọ lati w ani titi pa, ki wọn si se akiyesi daradara.

Bakan naa ni wọn ni ki wọn bojuto awọn ọdọkunrin ti wọn n da abẹ fun ni awọn agbegbe ori oke ni orilẹ̀ed naa, gẹgẹ bi asa ati ise ilẹ naa.

Igbesẹ naa pọn dandan lati jẹ ki awọn ọdọ da ọdọlangba laarin awọn ẹya Xhosa.

Bakan naa ni wọn gba awọn agbẹ ni imọran lati pese aabo to tọ fun awọn ẹranko lasiko otutu yii.

Amọ ko I tii han si gbangba boya oju ọjọ to n se segesege,Climate change ni nkan se pẹlu yinyin to n jabọ naa.