Paris 2024: Wo ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa ìdíje Olympics àti Paralympics ọdún yìí

O ku oṣu mẹfa bayii ti idije Olympics yoo fi bẹrẹ niluu Paris ni orilẹede France ti idije Paralympics to wa fawọn akanda eeyan naa yoo si tẹle e lẹyin ọsẹ diẹ.

Ayẹyẹ ibẹrẹ idije naa yoo waye ninu ọkọ oju-omi, afihan ijo jijo naa yoo waye nibi ayẹyẹ ọhun fun igba akọkọ.

Nigba wo ni idije Olympics ati Paralympics yoo bẹrẹ, awọn wo ni yoo kopa nibẹ?

Idije Olympics yoo bẹrẹ lọjọ kẹrindinlọgbọn oṣu Keje ọdun 2024 yii, yoo si pari ni ọjọ kọkanla oṣu Kẹjọ.

Awọn elere idaraya ẹgbẹrun mẹwaa ati abọ ni yoo kopa ninu ere idaraya mejilelọgbọn, ami ẹyẹ 329 lo wa nilẹ ti wọn yoo gba.

Idije Paralympics eyi to wa fawọn akanda ẹda naa yoo gberasọ lọjọ kejidinlọgbọn, yoo si pari ni ọjọ kẹjọ oṣu Kẹsan an.

Ẹgbẹrun mẹrin le ni irinwo elere idaraya ni yoo kopa ninu ere idaraya mejilelogun ninu idije ọhun, ati pe ami ẹyẹ 549 lo wa nilẹ ti wọn yoo ja fun.

Orilẹede igba ati mẹfa ni yoo kopa ninu idije Olympics niluu Paris, nigba ti orilẹede 184 yoo kopa ninu idije Paralympics.

Ilu Paris ti gbalejo idije Olympics lọdun 1900 ati ọdun 1924.

Ilu Paris ni yoo jẹ ilu keji to ti gbalejo idije Olympics ati Paralympics fun igba mẹta ọtọtọtọ lẹyin ti ilu London ti kọkọ ṣe bẹẹ.

Ilu Londo gbalejo awọn idije yii lọdun 1908, 1948 ati lọdun 2012.

Ilu Tokyo ni idije Olypics ti waye kẹyin lọdun 2021, ajakalẹ arun covid ni ko jẹ ko waye nigba to yẹ ki o waye.

Nibo lawọn ere idaraya Olympics yoo ti waye?

Gbọngan mẹẹdogun ni idije Olympics yoo ti waye nigba ti Paralympics yoo maa waye ni gbọngan mọkanla laarin gbungbun ilu Paris.

Idije triathlon, ere-ije gigun, odo wiwẹ ati idije Para-triathlon yo waye lẹgbẹ odo Seine niluu Paris.

Papa iṣere Stade de France ni yoo gbalejo awọn oniruuru ere sisa ati awọn ere idaraya mii.

Ilu mẹfa kaakiri awọn ẹkun to wa ni France ni ere bọọlu yoo ti waye.

Ilu Marseille to wa ni bebe okun ni ere idaraya ọkọ oju omi yoo ti maa waye.

Teahupo'o ni Tahiti ni awọn to n lefo lori omi to n ru yoo ti ṣe ere idaraya ti wọn.

Awọn to ṣakoso idije naa ni ọpọ ibi tawọn yoo lo fawọn ere idaraya OLympics ti wa nile tẹlẹ, eyi ṣi maa din owo nina ku, ati pe ko tun ni ṣakoba fun oju ọjọ.

Agbekalẹ awọn ibi ti wọn fẹ lo fun idije Olympics ni a gbọ pe yoo na ijọba ni biliọnu mẹjọ owo Yuro.

Alaga igbimọ abẹnu to n ṣakoso idije ọhun sọ pe ko ni si ewu lori owo nina fun idije naa.

Awọn ere idaraya tuntun wo ni yoo waye ni Olympics ọdun yii ni Paris?

Ere idaraya iji jijo yoo waye fun igba akọkọ ninu idije OLympics 2024 yii niluu Paris.

Irufẹ iji jijo bẹrẹ niluu New York lati bii ọdun 1970 siwaju.

Awọn ere idaraya tuntun mẹrin to bẹrẹ ni Tokyo Olympics yoo tẹsiwaju.

Amọ, idije Karate ati baseball ko ni si ninu Olympics 2024.

Bawo ni ayẹyẹ ibẹrẹ Olympics 2024 yoo ṣe ri gan an?

Awọn elere idaraya maa n saba n dara ninu ayẹyẹ ibẹrẹ idije Olympics ni papa iṣere ti idije ba ti n waye.

Niluu Paris, ninu odo lawọn elere idaraya yoo ti dara.

Oniruuru ikọ wẹdo-wẹdo ni yoo wa ọkọ oju omi fun iwọn kilomita mẹfa ninu odo Seine.

Ni papa iṣere Trocadero lawọn elere idaraya yoo peju si ti wọn yoo ti tan ina Olympics.

Awọn to n ṣe agbatẹru idije Olympics sọ pe awọn fẹ kawọn eeyan wo ayẹyẹ idije naa lọfẹẹ.

Awọn oluworan ti ko din ẹẹdẹgbẹfa ni ireti wa pe wọn o peju ayẹyẹ ibẹrẹ Olympics ninu odo Seine.

Kinni ere Paris 2024 gan an?

Ere meji ni o wa fun idije Olympics 2024 ti orukọ wọn si n jẹ "Les Phryges."

Wọn ṣe awọn ere ọhun bii fila "Phrygian" tawọn eeyan wọn lasiko ''French Revolution ọdun 1789, nigba ti wọn rọ ọba orilẹede France loye.

Ere keji Phryge ni abẹ tawọn akanda eeyan maa fi n sare, igba akọkọ ree ti ere yoo ni ami ipenija ara.

Ṣe orilẹede Russia naa yoo kopa ni Paris 2024?

Orilẹede Russia ati Belarus ko ni lanfani lati ran ikọ kankan lati lọ ṣoju wọn ninu idije Olympics ati Paralympics niluu Paris.

Idi abajọ naa ni ikọlu ti Russia ṣe si orilẹede Ukraine ati bi Belarus ṣe ṣatilẹyin fun un.

Amọ, awọn elere idaraya lati awọn orilẹede meji naa le kopa gẹgẹ ọlọdanni lai ni ṣoju orilẹede wọn.

Minisita ọrọ ilẹ okeeree fun Russia, Sergei Lavrov, bu ẹnu ẹtẹ lu ajọ IOC lori bi ko ṣe fi ofin de orilẹede Israel bakan naa lati ma le kopa ninu idije Olympics pẹlu nkan to n fi ileeṣẹ omogun rẹ ṣe ni Gaza.

Aarẹ ajọ IOC, Thomas Bach ṣalaye pe alaye naa ko jọ ara wọn, o si sọ pe Israel yoo kopa ninu Olympics ati Paralympics.

Awọn ogunlende naa yoo lanfaani lati kopa ninu idije Olympics 2024.

Ni Tokyo, awọn elere eje mọkandinlọgbọn lati orilẹede mọkanla to fi mọ Syria, South Sudan, Afghanistan, ati Cameroon lo kopa ninu idije Olympics.

Bawo ni mo ṣe le ri tikẹẹti ra lati wo Olympics ati Paralympics?

Tikẹẹti lati wo idije Olympics ati Paralympics ti wa lori atẹ kaakiri agbaaye fun ẹnikẹni to ba fẹ ra.

Amọ, lori itakun agbọrọkaye Paris 2024 nikan ni o ti le ri i ra.

Wọn tiẹ ra awọn kan tan, bi o ti n tan ni wọn tun ko omiran wa.

Iye ti wọn n ta tikẹẹti naa bẹrẹ lati £21 fun idije Olympics nigba ti Paralympics jẹ £13.

N jẹ ọpọ eeyan ni France mọ nipa Olympics ati Paralympics?

Iwadii kan fihan pe ida mẹrinlelogoji ninu ọgọrun lo ro wi pe bi ilu Paris ti n gbalejo idije Olympics ko dara.

Wọn ni owo ọkọ yoo di ilọpo meji niluu Paris lasiko ti Olympics ba n lọ lọwọ.

Inu tiẹ n bi awọn olugbe Paris mii pe idije Olympics yoo ṣakoba fun eto abo.

Ni apa ariwa ilu Paris ti wọn n pe ni Seine-Saint-Denis ni Olympics ati Paralympics Village wa.

Nibẹ naa ni wọn kọ ibi tawọn omuwẹ yoo ti maa ṣe ere idaraya wọn.

Ọpọ ajọ lo koro oju si bi ijọba ṣe yọ ilẹ lara awọn ile lati kọ ibi tawọn ere idaraya yoo ti waye.

Nibo ni Olympics ati Paralympics to kan lẹyin Paris 2024 yoo ti waye?

  • 2028 - Los Angeles, USA
  • 2032 - Brisbane, Australia
  • 2036 - nkan ninu India, Poland, Mexico tabi Indonesia ni yoo jamọ lọwọ