You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
WHO kéde ìgbáradì fún àjàkálẹ̀ ààrùn Disease X tó ṣéese kò tún mi àgbáyé
Awọn olori ẹka ilera lasiko ipade apero igbimọ World Economic Forum to waye ni Davos, ni orilẹede Switzerland ti bẹrẹ si n sọrọ lori idi pataki to fi yẹ ki agbaye bẹrẹ igbaradi fun itankalẹ aarun mii.
Aarun yii ni wọn pe orukọ rẹ ni ‘Disease x’.
Saaju ni ajọ eleto ilera (WHO) ti se ikilọ pe igbaradi fun aarun yii se koko lati dena irufẹ ajalu to waye lasiko Covid 19.
Itankalẹ aarun naa se akoba fun ẹka eto ilera, ti awọn orilẹede si padanu ọpọlọpọ owo nitori bi o se mu se akoba ba ọrọ aje wọn.
Ki ni Aarun Disease X?
Eyi ni orukọ ti ajọ eleto ilera WHO ya sọtọ fun aarun to seese ko tun tan kalẹ kaakiri agbaye, to ba bẹrẹ si ni kuro ni orilẹede kan si kan.
Wọn ti mọ nipa aarun yii saaju ki aarun Covid 19 to waye. O wa lara awọn aarun ti WHO se akọsilẹ rẹ lọdun 2018.
Bo tilẹ jẹ pe wọn ko ti i le sọ awọn ibi pato ti aarun Disease X le gba jade., amọ wọn ni orisun kan to daju ni lati ara awọn ẹranko kan.
Eto R&D jẹ igbesẹ agbaye ti ọpọ awọn eeyan fọwọsowọpọ lati dasilẹ. Ajọ eleto ilera, WHO, lo gbe eto kalẹ lati ri i pe igbaradi bẹrẹ.
Igbaradi yii jẹ igbesẹ lati ri pe iwadii ati ilana amojuto wa nilẹ fun ajakalẹ aarun to ba waye lojiji.
Idi fun igbesẹ yii ni lati le se awọn ayẹwo to tọ ni kiakia, ipese abẹrẹ ajẹsara ni kiakia ati awọn oogun to le doola ẹmi awọn eeyan to ba ni aarun yii ati fun idena de ajalu aarun naa.
A ri awọn itankalẹ aarun ni atẹyinwa bi Sars(Severe Acute Respiration Syndrome), Swine flu, Mers (Middle East Respiratory Syndrome), Ebola ati Covid 19.
Awọn eleto ilera mọ pe awọn eeyan n bẹru pe itankalẹ to n bọ yii le buru ju ti atẹyinwa lọ tabi se nnkan to buru ju nnkan ti Covid 19 da silẹ lọ.
Awọn ibi ti Disease X le gba jade
Nitori agbara to ni lati di ajakalẹ aarun, awọn aarun yii ni WHO tọka si pe o le jẹ atọna rẹ:
- Crimean-Congo hemorrhagic fever
- Covid-19
- Ebola
- Marburg
- Lassa fever
- Zika
- Nipah
- Rift Valley fever
- Middle East respiratory syndrome (MERS)
- severe acute respiratory syndrome (SARS)
- Zoonotic viruses
- Bacterial Infection
Awọn ami ti Disease X le fihan ni ara
Gẹgẹ bi ajọ WHO ṣe sọ, arun tuntun yii le bẹrẹ bi aisan iba, irora ninu iṣan ara, aarẹ ara, ọrun didun, ẹyin didun, ori fifọ, oju wiwu, ati ki eeyan o ma le wo imọlẹ.
Yatọ si awọn ami ti a kọkọ darukọ, Disease X tun le fa ki ara deedee ma a kan eeyan. Lẹyin ọjọ diẹ, o le di airoorun sun, ipaya ati ki eeyan o fẹ ẹ da wa.
Inu rirun nibi oke ikun naa le jẹyọ, ẹdọ naa si le wu.
Se Disease X le fa itankalẹ aarun?
Aarun Disease X ni ọpọ ko mọ nipa rẹ sugbọn o ti wa nilẹ. Awọn oniwadii ninu imọ sayẹnsi ati awọn to ni oye nipa eto ilera gbagbọ pe awọn le pese ẹrọ lati koju aarun yii to ba fẹ yiwọ di ajakalẹ aarun.
Nibi ipade World Economic Forum l'ọsẹ to kọja, igbimọ kan ti wọn pe ni “Igbaradi fun aarun Disease X”, eyi ti Ọga agba WHO, Dokita Tedros Adhanom Ghebreyesus lewaju fun, salaye nipa gbogbo igbesẹ to yẹ lati gbe lati se igbaradi fun awọn eleto ilera fun ilakọja to n bọ ti aarun naa ba di itankalẹ.
“Awọn eeyan n sọ pe eyi le da ibẹruboju silẹ. O dara pe ka gbaradi silẹ fun nnkan to le waye nitori irufẹ rẹ ti waye saaju.”
Bawo ni ajọ eleto ilera se n gbaradi fun itankalẹ aarun to n bọ?
Dokita Tedros salaye nibi ipade apero World Ecomomic Forum pe ajọ WHO ti bẹrẹ si ma gbe awọn aṣẹ kan kalẹ lori igbaradi fun itankalẹ aarun mii.
Eyi nii ṣe pẹlu owo fun gbigbọ bukaata itankalẹ ati lilo ibudo imọ ẹrọ to wa ni orilẹede South Africa, to jẹ ibi ti wọn yoo ti ma peseabẹrẹ ajẹsara.
Ajọ European Centre for Disease Control And Prevention, sọ ninu abọ iwadii kan fun ọdun 2022 pe, agbaye le ṣamulo awọn ilana amojuto ajakalẹ aarun to wa nilẹ tẹlẹ, dipo ṣiṣe tuntun.
Bakan naa ni wọn gba imọran pe ki wọn se ayẹwo awọn ilana tuntun saaju ki ajakalẹ aarun to o bẹrẹ.