You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Awùjalẹ̀ fi òye Gbọ́baníyì tí ìlú Ìjẹ̀bú dá Mallam El-Rufai lọ́lá
Gomina tẹlẹ nipinlẹ Kadanu, Mallam Nasir El-Rufai ni wọn ti fi jẹ oye Gbobaniyi ti ilu Ijebu nipinlẹ Ogun.
Ayẹyẹ ifinijoye naa waye ni Ọjọ Satide, ọjọ kẹrindinlogun oṣu kejila ọdun 2023 ni aafin Awujale ti ilu Ijẹbu, Oba Sikiru Adetona.
El-Rufai ni yoo jẹ ẹni akọkọ ti ko ki n se ọmọ Yoruba ti yoo gba oye lati ọwọ Awujale ti ilu Ijebu.
Nigba to n kede bi inu rẹ se dun lori ayelujara, El-Rufia ni oun fi ayọ kede pe oun yoo jẹ ẹni akọkọ ti ko ki n se ọmọ Yoruba ti yoo tẹwọgba oye lasiko Oba Adetona.
Bakan naa ni Awujale yoo tun ma fi oye da Otunba Jimi Lawal ati iyawo rẹ, Maryam Lawal lọla fun ipa to n ko ninu ilọsiwaju ilu Ijẹbu.
“Mo ni ayọ lati kede pe lọjọ Satide ọjọ kẹrindinlogun oṣu kejila ọdun 2023, Ọba Sikiru Kayode Adetona, Awujale ti ilu Ijebu yoo fi oye da ẹgbọn mi, Ọtunba Jimi Lawal ati iyawo rẹ, Maryam Lawal lọla fun ipa ti wọn n ko ninu ilọsiwaju ilu Ijebu.
“Inu mi lati sọ fun iyi pe emi ni ẹni akọkọ ti ko ki n se ọmọ Yoruba ti tẹwọgba oye lati ọwọ Awujalẹ,
“Ni bayii, emi ni Gbọbaniyi ti ilu Ijẹbu. Mo dupẹ lọwọ Kabiyesi fun idanimọ yii, mo si dupẹ lọwọ awọn to fẹ ire fun mi lori oye yii.”