Rògbòdìyàn Iraq fẹjú si, àdó olóró àti ìbọn ń dún lákọlákọ

Ko din ni eeyan mẹtalelogun ti wọn pa bayii nibi ija igboro to n waye ni olu ilu orilẹ-ede Iraq, Baghdad, lẹyin ti oloṣelu kan ni oun ko ṣe oṣelu mọ.

Niṣe ni iro ibọn ati nkan abugbamu n dun lakọlakọ lasiko ti awọn alatilẹyin olori ijọ ẹlẹsin Islam, Shia. Moqtada al-Sadr, yabo ile ijọba.

Awọn agbofinro ti kede pe ọpọlọpọ eeyan lo tun farapa.

Ṣugbọn Ọgbẹni Sadr ti paṣẹ fun awọn alatilẹyin naa, lati kuro niwaju ile aṣofin ti wọn wa, nibi ti wọn ti n ṣe iwọde fun ọpọlọpọ ọsẹ.

Lati ọdun 2021 ni nkan ko ti fararọ ni Iraq nitori eto idibo ti wọn ko ṣe yọri.

Igun Ọgbẹni Sadr lo ni aṣofin to pọ julọ ninu idibo oṣu Kẹwaa ọdun to kọja, ṣugbọn wọn kuna lati fẹnuko pẹlu igun keji to tun ni aṣofin to pọ, lori idasilẹ ijọba tuntun.

Ẹ dakun, ẹ dawọ iwọde duro - Sadr bẹ awọn alatilẹyin rẹ

Sadr, ni owurọ ọjọ Iṣẹgun, rawọ ẹbẹ si awọn eniyan orilẹ-ede Iraq, fun rogbodiyan naa , to si paṣẹ fun awọn alatilẹyin rẹ pe ki wọn dawọ iwọde wọn duro.

“Igbesẹ yii ti kuro ni eyi ta fi n wa ayipada, nitori pe o ti sọ ilana alaafia nu.

“Eewọ ni lati ta ẹjẹ awọn ọmọ Iraq silẹ.”

Lẹyin to sọ ọrọ yii lori amohunmaworan ni awọn ologun gbẹsẹ kuro lori ofin isede ti wọn fi sita lọjọ Aje.

O ti le ni ogun ọdun ti Moqtada al-Sadr, ẹni ọdun mejidinlaadọta, ti jẹ gbajugbaja ati oloṣelu ni Iraq.

Ikọ ọmọ ogun agbebọn rẹ, Mehdi Army to pada sọ orukọ rẹ ni Peace Brigades, , si wa lara awọn to doju ija kọ America ati awọn ọmọ ogun Iraq tuntun, lẹyin ogun to waye lọdun 2003 to gba ijọba danu lọwọ Saddam Hussein.

Olotu ijọba ilẹ Iraq ti wa bẹbẹ pe ki alaafia jọba pada.

Oru mọju tun ni ija oju popo tun bẹrẹ nigba tawọn onija ọhun bẹrẹ si yinbọn lakọlakọ, ija yii si lo tii buru julọ ninu laasigbo to tii waye ri lorilede Iraq.

Bawo ni laasigbo naa se waye?

Awọn agbofinro ni wahala naa lo bẹrẹ laarin awọn agbofinro alaafia to n se atilẹyin fun Sadr atawọn ikọ ọmọ ogun orilẹede naa.

Awọn fọnran fidio to si gba ori ayelujara kan lo n se afihan awọn agbofinro alaafia naa, ti wọn n lo awọn ohun ija oloro, to fi mọ ado oloro pẹlu.

Orilede Iran, tii se orilẹede alamuleti Iraq, ti wa ti awọn nu bode rẹ pa nitori laasigbo naa, ti orilẹede Kuwait si ti paroko ransẹ sawọn ọmọ orilẹede rẹ, lati kuro ni Iraq kiakia.

Awọn osisẹ eleto ilera ti wa kede pe eeyan mẹẹdogun to n se atilẹyin fun Sadr ni wọn ti yinbọn pa ninu wahala naa, ti o kere ta, eeyan ọtalelọọdunrun o din mẹwa (350) si fi ara pa yannayanna.

Wayi o, agbẹnusọ fun akọwe apapọ fun ajọ isọkan orilẹede agbaye, UN, Antonio Guterres ti kede pe ominu n kọ oun lori awọn isẹlẹ to n waye ni Iraq.

O wa bẹbẹ pe ki wọn tete gbe igbesẹ lati pinwọ rogbodiyan naa, ko to fẹju ju bayii lọ.