Àwọn olùdíje fún ipò Aláàfin yóò bẹ̀rẹ̀ ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò lọ́jọ́ Ajé

Eto gbogbo lati yan Alaafin tuntun fun ilu Ọyọ ṣi n tẹsiwaju bayii pẹlu bi ọpọlọpọ ọmọ oodua jakejado agbaye ṣe n fi oju sọna fun yiyan Alaafin miran.

Ipade awọn afọbajẹ ilu Ọyọ, Ọyọmesi waye ni Ọjọbọ nibiti wọn ti fẹnuko lori pe ki gbogbo awọn ọmọ oye to n dije fun ipo Alaafin o wa fun ipade binukonu kan lọjọ Abamẹta ni gbọngan Agbala Ogun to wa ni afin Alaafin.

Ohun miran to jẹyọ nibi ipade naa ni afẹnuko lori ifọrọwanilẹnuwo fun gbogbo awọnoye to n dije fun ipo Ọba alade naa.

Lati ọjọ Aje ọjọ karun un titi di ọjọ karundinlogun oṣu kẹjọ ni ifọrọwanilẹnuwo Atẹjade kan ti agbẹnusọ fun Alaafin, Bode Durojaiye, fi ransẹ si ileeṣẹ

BBC, ifọrọwanilẹnuwo naa yoo maa waye, yatọ si ọjọ Ẹti lati lee fun awọn eeyan lanfani lati lọ kirun jimọ.

Baba Iyaji ti gbe orukọ ọmọoye mẹrindinlaadọrun siwaju Ọyọmesi

Olori ọmọọba nilu Ọyọ, ti wọn n pe ni Baba Iyaji ti ilu Oyo, Oloye Mukaila Afonja ti ṣe agbekalẹ orukọ ọmọ oye mẹrindinladọrun to n dije fun ipo ọba Alaafin siwaju Basorun to jẹ igbakeji Alaafin Ọyọ, Oloye Agba Yussuf Akinade Ayoola Layinka. 

Ikede naa waye lẹyin ti awọn Oyo Mesi ṣe ipade i niluu Oyo.

Basorun ilu Oyo, Oloye Akinade Yussuf Layinka ti ṣe afọmọ ọrọ lori ilana ti wọn yoo fi jẹ Alaafin tuntun lẹyin ti Alaafin Ọlayiwọla Adeyẹmi kẹta gbesẹ ni ibẹrẹ ọdun 2022.

Baṣọrun ilu Ọyọ ṣalaye ninu atẹjade naa pọn dandan lati yannana awọn igbesẹ naa lati dẹkun gbọyisọyi ati iroyin irọ ti awọn eeyan kan n gbe kiri lori ayelujara.

Ifa lo ṣi n yan eeyan sori itẹ Alaafin lode Ọyọ - Baṣọrun ilu Ọyọ

O ni laipẹ yii ni iroyin kan gba ori ayelujara kan pe awọn Ọyọmesi to jẹ afọbajẹ ilu Ọyọ lo ni aṣẹ lati fi ọmọ oye to ba wu wọn jọba, ati pe kii ṣe ifa ni wọn n tẹle lati yan Alaafin lode Ọyọ.

Ọṣọrun Layinka ni irọ nla leyi nitori pe nitori pe ipo to ṣe pataki ninu iran Yoruba ni ipo Alaafin jẹ, iwadi to jina denu si gbọdọ lati mu ẹni ti ipo naa tọ si.

O ni bi o tilẹ jẹ pe nnkan ti yatọ si igba iwasẹ to jẹ wi pe kii ju ọmọ oye meji to maa n du itẹ Alaafin, sibẹ Oyomesi ko le da iṣẹ yii jẹ lai lọwọ Ifa nibẹ.

“Ko si bi a ṣe fẹ lo ọgbọn inu ati oye wa lati yan ọkan ninu awọn ọmọ oye to le ni ogoji lati fi jẹ Alaafin, kii ṣe ohun to rọrun lati ṣe rara.

“Lẹyin ayẹwo fun awọn ọmọ oye to fifẹ han lati jẹ oye Alaafin, ti a si ti ja awọn kan kuro, ohun to kan ni lati kan si ifa lati yan ẹni to ka oju ilu ninu wọn.”

Basorun ilu Ọyọ ni awọn ko gbọdọ tori owo tabi iwa imọtara ẹni nikan yan eeyan sori itẹ Alaafin, nitori pe Alaafin kii ṣe Ọba ilu Ọyọ nikan, Ọba ilẹ Yoruba ni.

Basorun sọ síwájú pé lẹ́yìn èyí ni àwọn ṣẹ̀ṣẹ̀ máa pe gbogbo wọn jọ láti bá gbogbo wọn sọ̀rọ̀ lórí ìdí tó yẹ kí wọ́n gba àláfíà láàyè láàárín ara wọn lásìkò àti lẹ́yìn yíyan ẹni tí ipò náà yóò padà já mọ́ lọ́wọ́.

“Ìrẹ́pọ̀ gbọ́dọ̀ wà láàárín àwọn tó ń wá ipò kí ìlú le rojú ráyè, èyí tó máa fún Oyomesi ní àǹfàní láti ṣe iṣẹ́ wọn bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ.”

Bakan naa ni Baṣọrun ilu Ọyọ naa wa ke sawọn to n gbe iroyin ofege jade nipa ọrọ oye Alaafin jijẹ lode Ọyọ lati lọ simẹdọ ki wọn dẹkun kikọ awọn iroyin to le e da omi alaafia ilu Ọyọ ati ilẹ Yoruba ru.

Ki ni awọn iroyin to ti waye saaju lori iyansipo Alaafin tuntun:

Arúmọjẹ lorúkọ ọmọọba 58 táwọn afọbajẹ gbé jáde fún ipò Alaafin - Ọmọọba ìdílé Adeitan

Arumọjẹ lasan ni iwe orukọ awọn ọmọoye lati idile Agunloye ti wọn gbe sita gẹgẹbi awọn to ku ninu ilana yiyan alaafin tuntun fun ilu Ọyọ.

Ọkan lara awọn ọmọọba ilu Ọyọ lati idile Adeitan, Ọmọọba Afọlabi Ademọla Adeṣina lo ọ eyi ninu atẹjade kan to fi sita lẹyin ti iroyin jade pe awọn afọbajẹ ilu Ọyọ ti yọ orukọ awọn ọmọoye mọkanlelọgọta kuro lara awọn to n du itẹ naa, leyi to wa fi ku mejidinlọgọta.

Ọmọọba Adeṣina ṣalaye ninu atẹjade naa pe ijọba ko lee gbarale agbekalẹ iwe ofin oyejijẹ tọdun 1961 ti wọn pe ni “1961 declaration” lati yan Alaafin tuntun.

O ni iwe ofin oye jijẹ ijọba ipinlẹ Ọyọ ti ijọba fọwọ si loṣu keje ọdun 2001 nikan ni o tọna fun oye jijẹ.

“arumọjẹ lasan ni iroyin pe wọn ti buwọlu orukọ ọmọ oye mejidinlọgọta, ti wọn si gba orukọ mọkanlelọgọta si ẹgbẹ nitori pe igbesẹ bẹẹ ko lee duro niwaju ofin.”

O ni kan lara awọn oṣiṣẹ agba ni ijọba ibilẹ Atiba lo “kan an nipa fun Baba Iyaji lati pe ipade pẹlu idile Oye Agunloye lati tọka si awọn to jẹ ọmọ idile wọn ninu awọn mọkandinlọgọfa to fi ifẹ han si didu ipo ọba naa.

“Abaje ipade ti ko bofin mu yii ni wọn ti gbe e jade pe wọn ti yọ ọwọ ọmọ oye mọkanlelọgọta to jẹ ọmọọba lati iran Atiba kuro lawo idije ipo Alaafin Ọyọ.”

O wa ke si ijọba ipinlẹ Ọyọ pe ko jẹ ki ọrọ gbogbo to wa niwaju ile ẹjọ nipa ọrọ oye alaafin ilu Ọyọ yanju na ki o to lee sọ boya ọmọoye kan lẹtọ tabi ko lẹtọ lara awọn mọkandinlọgọfa to n du ipo naa.