Ọwọ́ EFCC tẹ ọmọ Yahoo 48 àti babaláwo kan ní Kogi

EFCC

Oríṣun àwòrán, EFCC

Ajọ to n gbogun ti iwa ajẹbanu ni Naijiria, EFCC, ti fi ṣikun ofin mu afurasi ọmọ yahoo mejidinlaadọta nipinlẹ Kogi.

EFCC tun mu babalawo kan pẹlu awọn eeyan naa lori ẹsun igbimọpọ ati fifi ọna ẹburu gba owo lọwọ ẹlomiran.

Ikọ ajọ ọhun to n ṣiṣẹ ni ipinlẹ Kwara, Kogi ati Ekiti, ti olu ọọfisi rẹ wa ni niluu Ilorin lo mu awọn afurasi naa.

Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ EFCC lagbegbe naa, Dele Oyewale fi lede, sọ pe ọwọ awọn tẹ awọn afurasi naa niluu Lokoja.

O ni babalawo ti wọn mu ni igbagbọ wa pe o jẹ ẹni to maa n ṣe aajo fun awọn afurasi naa.

Atẹjade EFCC ni oniruru oogun abẹnu gọngọ ni wọn ba lọwọ babalawo naa.

Lara awọn dukia ti EFCC gba lọwọ awọn afurasi ọhun ni ọkọ bọgini mẹwaa, alupupu meji, kọmputa alagbeka mọkanla, ẹrọ ibaraẹnisọrọ mẹtalelọgọrin ati oniruru oogun.

Atẹjade ọhun ni ọjọ ori awọn afurasi naa ko ju ọdun mẹtadinlogun si mẹrinlelọgbọn lọ.

EFCC pari atẹjmade rẹ pe awọn afurasi ọhun yo foju bale ni kete ti iwadii ba pari lori ẹsun ti wọn mu wọn fun.