Ẹ wo ìdí táwọn ìyálọ́mọ fi ń jẹ Olubi, àti ọ̀pọ̀ ọ̀nà tí wọ́n ń gbà jẹ ẹ́

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Yoruba ni tibi tire la dale aye, tibi tire la se ẹ́da eeyan, bi aye ire se wa, naa ni aye ibi wa.
Ni ọjọ ikunlẹ ti alaboyun ba bimọ tan, bi wọn ba se n gbe ọmọ tuntun jade, ti Yoruba gbagbọ pe ire ni, naa ni wọn yoo tun gbe asopọ ẹjẹ ati ẹran jade ni ikun alaboyun, ti wọn n pe ni Olubi.
Olubi ọmọ yii si lo jẹ iwulo fun ọmọ tuntun, lasiko to ba wa ninu oyun.
Eyi lo n pese afẹfẹ́ fun lati ara iya rẹ amọ olubi yii ko wulo kankan mọ̀, boya fun ọmọ tabi iya rẹ lẹyin ibimọ.
Ṣugbọn iyalẹnu lo jẹ lati gbọ pe awọn iyalọmọ kan maa n se olubi ọmọ yii, ti wọn yoo si jẹ bii ounjẹ lẹyin ti wọn ba bimọ tan nitori awọn idi kan to han si awọn nikan.
Nibayii, awọn onimọ iwadii ni Fasiti Northwestern ti wa sekilọ fun awọn iyalọmọ lati dẹkun jijẹ olubi ọmọ wọn nitori ọpọ ewu to wa ninu rẹ.
Isẹ ti awọn iyalọmọ ni Olubi n se ninu ara ti wọn fi n jẹ ẹ
Awọn kan gbagbọ pe jijẹ ibi ọmọ kun fun ọpọlọpọ ohun aṣaralore bi Vitamin, to le se anfaani fun ilera obinrin, ti ọpọ awọn eeyan si ti gunle fun igba pipẹ.
Bakan naa ni awọn kan sọ pe o fi abiyamo ni okun, to si ma ṣe anfaani fun omi ọmu ati awọn nnkan mi to ṣe ara loore.
Fun awọn mii, jijẹ rẹ le mu adikun ba irẹwẹsi ọkan fun abiyamọ lẹyin to ba bimọ, ati pe o tun le mu adikun ba inira ti obinrin n koju .
Siwaju si, awọn kan tun gbagbọ pe jijẹ ibi ọmọ ma mu ibaṣepọ to dan mọran wa laarin iya ati ọmọ sugbọn awọn anfaani yii ni wadi ijinlẹ sayẹnsi ko le fidi rẹ mulẹ rara.
Sugbọn iwadi Fasiti Northwestern ni ko ri ẹri kankan to safihan pe anfani wa ninu rẹ tabi ijamba wa ninu jije ibi ọmọ.
Ileẹkọ Royal Midwives gbagbọ pe to ba wu obinrin, o le ni oun fẹ jẹ ibi ọmọ.
Wo oniruuru ọna tawọn iyalọmọ n gba jẹ Olubi ọmọ
Awọn onimọ iwadii yii ni olubi jẹ okun to n gbe afẹfẹ 'oxygen' atawọn eroja mi lati ara iya si ara ọmọ ninu oyun.
Okun ọhun tun maa n fa awọn idọti inu ẹjẹ ọmọ kuro.
Wọn fikun pe jijẹ olubi yii ko ṣiṣẹ kankan lara awọn iya ikoko, ko si tọ ki wọn maa jẹ.
Aṣa ki iya maa jẹ olubi ọmọ yii bẹrẹ si n gbilẹ si lẹyin ti awọn gbajumọ kan atawọn alẹnulọrọ lori ayelujara bẹrẹ si n sọ iriri wọn lẹyin ti wọn jẹ olubi ọmọ wọn tan.
Iroyin ni awọn obinrin kan maa n jẹ olubi naa ni tutu lai ṣe e, nigba ti awọn mii a maa se tiwọn, ti awọn miran a si maa yan ti wọn ki wọn to jẹ.
Yatọ si jijẹ Olubi, awọn mii maa n lọ olubi naa pẹlu awọn eso mii, ti wọn a si mu bii ẹni mu ẹlẹrindodo.
Ewu to wa ni jijẹ́ ibi
Ninu imọ eto ilera, bii idọti ni olubi ọmọ ri lẹyin ọjọ ikunlẹ nitori awọn kokoro aifojuri kan maa n wa lara rẹ."
Awọn onimọ sọ siwaju si pe pupọ obinrin to n jẹ olubi ọmọ wọn n ṣe bẹẹ lode oni nitori wọn ri awọn akẹẹgbẹ wọn to n ṣe bẹẹ.
Onkọwe kan, Cynthia Coyle, onimọ-jinlẹ nipa ile-iwosan ni Ile-ẹkọ giga Northwwest, ni awọn obinrin to yan jijẹ ibi ọmọ, ni lati ṣọra pupọ nipa ohun ti wọn fi sinu ara wọn lasiko oyun ati titọju ọmọ.
O ni ko si ilana kankan nipa bi a ṣe le fi ibi ọmọ pamọ tabi ṣe jẹ.
“Awọn obinrin yii ko mọ nnkan ti wọn n fi sinu arawọn.”
Louise Sliverton ti ileẹkọ Royal College of Midwives ni ko si ẹri to peyw lati gba awọn obinrin ni imọran pe ki wọn ma jẹ ibi ọmọ.
“O wu obinrin bẹẹ ni.
“Amọ wọn gbọdọ mọ pe gẹgẹ bi ounjẹ ti a n gbe si ile, ni ibi ọmọ to si le bajẹ.
Fun idi eyi wọn ṣe gbọdọ sọra ni bi ti wọn ba gbe pamọ si ati bi wọn yoo ṣe gbe pamọ."
O fikun ọrọ rẹ̀ pe ti obinrin ba fẹ gbe igbesẹ yii, o ni lati ba agbẹbi sọrọ saaju ko to bimọ lati le ṣe eto bi yoo ṣe ri ibi ọmọ naa gba.
Dokita Daghni Rajasingam, agbẹnusọ fun ileẹkọ Royal of Obstetricians and Gynaecologists sọ pe oun ko ni gba obinrin ni amọran pe ko jẹ ibi ọmọ.















