‘Ó di dandan kí Oyetola fi ipò sílẹ̀ ní Nobember 27- Ademola Adeleke

Ikọ agbẹjọro fun Gomina ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan ni ipinlẹ Ọsun, Sẹnetọ Adeleke ti sọ pe ounyẹ kan ko lee yẹ gbigba ijọba lọwọ gomina Adegboyega Oyetọla lọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu kọkanla ọdun 2022.

O ni gbogbo iroyin to n kiri pe ile ẹjọ ni ki ajọ INEC lọ ko iwe ẹri Senetọ Adeleke wa ko l’ẹsẹ nlẹ rara.

Agbẹjọro fun Senetọ Adeleke, Amofin Niyi Owolade ṣalaye ọrọ yii ninu ọrọ to ba BBC News Yoruba sọ.

O ni gbogbo iroyin to n kaakiri pe ile ẹjọ to n gbọ awuyewuye abajade idibo gomina Osun to waye loṣu keje ti paṣẹ pe ki wọn lọ ko iwe ẹri Senetọ Adeleke wa kii ṣe otitọ.

Bakan naa ni ẹgbẹ oselu PDP pelu sọ pe yiyi ootọ lọrun ni iroyin naa nitori pe ko si ohun to jọ aṣẹ yii rara.

‘Iwe fọọmu CF 001 ni Oyetọla fẹ fi aṣẹ ofin beere, ile ẹjọ ko si tii gba fun un’

Ninu alaye to ṣe fun BBC News Yoruba, amofin to n lewaju ikọ agbẹjọro fun Senetọ Ademọla Adeleke, Ọgbẹni Niyi Owolade sọ pe ko si igba kankan ti ile ẹjọ ni ki wọn mu iwe ẹri Adeleke wa.

‘Adeleke yoo gba ijọba lọjọ kẹtadinlogbọn osu kọkànlá'

O ni ohun ti awọn olupẹjo n beere fun ni pe ki ile ẹjọ kan an nipa pe ki alakoso ajọ INEC wa farahan gẹgẹ bi ọkan lara awọn eleri awọn.

'' ki o si mu iwe akọsilẹ nipa oludije, iyen Form CF 001 wa siwaju ile ẹjọ, eleyi ti awọn si tako niwaju ile ẹjọ.''

Lẹyin naa ni ile ẹjọ si sun igbẹjọ si ọjọ Aje to n bọ tii ṣe Ọjọ Kọkanlelogun, Oṣu Kọkanla, 2022.

Amofin Owolade tun salaye pe igbẹjọ to n lọ lọwọ ko lee di ayipada ijọba ni ipinlẹ Ọṣun eyi ti yoo waye lọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu kọkanla ọdun 2022 pada.

O ni ko si idi fun awọn ewyan ipinlẹ Ọsun lati ko aya soke pelu ohun to pe ni “ọgbọn fifi ẹjọ falẹ” to ni awọn agbẹjọro fun gomina Oyetọla n lo ati pe aipari ẹjọ naa ko tumọ si wi pe gomina Oyetọla ko ni fi ipo silẹ fun Senetọ Ademọla Adeleke to bori idibo loṣu keje

INEC gbọ́dọ̀ mú ìwé ẹ̀rí ẹ̀kọ́ Ademola Adeleke síta, ilé ẹjọ́ pàṣẹ fún alákoso àjọ ètò ìdìbò nípínlẹ̀ Osun

Ile ẹjọ to n gbọ ẹjọ nipa esi idibo gomina nipinlẹ Ọṣun ti paa laṣẹ fun ajọ eleto idibo Naijiria, INEC lati ko awọn iwe orukọ oludije ati iwe ẹri ti ile ẹkọ ti Sẹnetọ Ademọla Adeleke, oludije fun ipo gomina lẹgbẹ oṣelu PDP lo fi dije lọdun 2018.

Ikọ agbẹjọro fun gomina ipinlẹ Ọṣun, Gboyega Oyetọla lo beere fun awọn iwe naa niwaju igbimọ naa, eyi to mu ki igbimọ ọhun paṣẹ fun alakoso ajọ INEC nipinlẹ Ọṣun pe ko ko awọn iwe naa wa.

Gboyega Oyetọla gbe Sẹnetọ Ademọla Adeleke, oludije PDP lọ siwaju ile ẹjọ lati tako esi ibo to gbe e wọle gẹgẹ bii gomina ipinlẹ Ọṣun loṣu keje.

Nigba ti igbẹjọ tẹ siwaju lọjọru, agbẹjọro fun Oyetọla, Amofin Abiọdun Saka Layọọnu SAN sọ fun ile ẹjọ naa pe awọn ti kọwe ipe kan si ile ẹjọ naa lati pa a laṣẹ fun alakoso ajọ INEC nipinlẹ Ọṣun pe ko mu iwe orukọ oludije ti wọn pe ni Form CF 001 wa pẹlu gbogbo awọn iwe ẹri oludije naa to lo lọdun 2018.

Agbẹjọro fun INEC, Paul Ananaba, SAN tako ipe naa nitoripe gẹgẹ bi o ṣe sọ, ko si eyi ninu iwe ipẹjọ kotẹmilọrun ti wọn pe tako esi idibo naa.

Ninu ọrọ to ba awọn akọroyin sọ lẹyin igbẹjọ, amofin Yọmi Aliyu to jẹ ọkan lara awọn agbẹjọro fun Oyetọla ni awọn n pe ipe naa lati lee mọ bi ọrọ ṣe jẹ pẹlu iwe ẹri ti Adeleke fi han ajọ INEC ṣe jẹ.

“Ile ẹjọ gbọdọ ri iwe ẹri to sọ pe oun ni yii. Idi niyi ti ariyanjiyan fi gbona janjan ni ile ẹjọ fun bii wakati meji pẹlu bi wọn ṣe n pe fun wiwọgile iwe ipe yii.”