Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́

Àkọlé fọ́nrán ohùn, Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Ojú mi ni omi ṣe wọ́ ìyàwó àti ọmọ mi lọ, èèyàn mẹ́sàn-án ni èmi nìkan pàdánù

Eyi ni ọrọ to jade lenu Adamu Yusuf niluu Mokwa, ipinlẹ Niger nibi ti ẹkun omi ti ṣọṣẹ lopin ọsẹ

Ajọ NEMA sọ pe o le ni igba eeyan to ba ẹkun omi naa lọ

Ti ẹgbẹrun mẹta si ti di alainilelori ati pe wọn ṣi n wa àwọn to dawati

Oju orun ni awọn eeyan naa wa lasiko ti ẹkun omi naa fi ṣọṣẹ

xxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxx

Igbakeji ọga ile ẹkọ Complete Child Development College to wa niluu Akure, Alexander Rotifa ti wa lẹsẹ kan aye ẹsẹ kan ọrun

Lẹyin ti iya akẹkọọ ran awọn janduku lati lu u nitori ko gba ọmọ rẹ laaye lati fi foonu jiwe wo lasiko idanwo WAEC ti wọn n kọ lọwọ

Ijọba Ondo ati ileeṣẹ ọlọpaa ni iwadii ti bẹrẹ lori iṣẹlẹ naa

xxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxx

Ọkunrin kan ko si gbaga ọlọpaa ni India

Fẹsun wi pe o fẹ ko awọn ejo oloro ti ko wọpọ wọ orilẹ naa

Awọn ejo to fi mọ paramọlẹ oloro mẹtadinlọgọta ni wọn ba ninu ẹru ọkunrin naa.

Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́