Israel fòfin de akọ̀wé àjọ UN pé kò gbọdọ̀ wọ ilẹ̀ rẹ̀ mọ́

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ijọba orilẹede Israel ti fi ofin de akọwe agba ajọ iṣọkan agbaye, Un, Ọgbẹni António Guterres, pe ko gbọdọ wọ orilẹede naa mọ.

Minisita fọrọ okeere lorilẹede Israel, Israel katz, ninu atẹjade kan to fi sita, tọka si Gutarres gẹgẹ bi “akọwe agba to n ṣe alatako orilẹede Israel to si n ṣe agbodegba fun awọn agbesunmọmi.”

Ninu ọrọ to fi si oju opo X rẹ, lẹyin ti orilẹede Iran rọ ojo ọgọsan ado oloro si Israel, Guterres ni oun bu ẹnu atẹ lu “ bi wahala ṣe n fẹju lẹkun ilẹ Larubawa lagbaye, pẹlu bi wahala kan ṣe n gori omiran” to si ni gbogbo igbesẹ ogun wọnyii “gbọdọ dopin.

O ni “alaafia ati iwa jogun o mi” ni ẹkun naa nilo bayii, amọṣa ko tọka si ikọlu Iran ni pato.

Nigba ti oun pẹlu n fi atẹjade sita lọjọru, Katz kede akọwe agba ajọ iṣọkan agba ye naa gẹgẹ bi ẹni eewọ lorilẹ Israel, pẹlu asọye pe ẹnikẹni ti “ko ba le sọ oju abẹ ọrọ niko nipa bibu ẹnu atẹ lu ikọlu orilẹede Iran lori ilẹ Israel ko lẹtọ lati fi ẹsẹ rẹ tẹ ori ilẹ orilẹede Israel.”

O na ika aleebu si Guterres fun ohun to pe ni “awọn igbesẹ to tako Israel to n gbe lati igba ti ogun naa ti bẹrẹ”.

Ikọlu ti Iran ṣe si Israel ni Ọjọ Iṣẹgun ni akọtun wahala to ti n waye lẹkun naa bẹrẹ lati nnkan bi ọdun kan sẹyin pẹlu bi Hamas ṣe kọlu Israel titi kan wahala laarin ẹgbẹ Hezbollah ti orilẹede Iran n ṣe agbodegba fun, at ikọ ogun Isreal.

Orilẹede Israel ṣigun wọ Gaza nitori ikọlu awọn ọmọogun Hamas to kọlu ẹkun gusu Israel lọjọ keje oṣu kẹwaa ọdun 2022 nibi ti wọn ti pannkan bii ẹgbẹfa eeyan ti wọn si ji ọtalelugba o din mẹsan an gbe lọ.

Lati igba naa, Israel ti ṣigun wọ Gaza, igbesẹ naa si ti gba ẹmi awọn eeyan to le ni ẹgbẹrun mọkanlelogoji, gẹgẹbi akọsilẹ ti ileeṣẹ eto ilera ẹgbẹ Hamas n fi sita.

Laarin asiko ikọlu yii, ọpọ igba ni edeaiyede ti waye laarin Israel ati ajọ iṣọkan agbaye lori bi nnkan ṣe n lọ si lagbegbe Gaza ati West Bank.

Bakan naa ni orilẹede Israel ati ajọ iṣọkan agbaye tun gbe ina wo oju ara wọn lori ipa ti ajọ aṣatipo labẹ ajọ naa n ko fun awọn ogunlende ọmọ ni Palestine.

Ni oṣu kinni ọdun yii, orilẹede Israel fi ẹsun kan awọn oṣiṣẹ ajọ naa kan pe wọn lọwọ si ikọlu to waye lọjọ keje oṣu kẹwaa ọdun 2022 ti ajọ naa si ni awọn ti bẹrẹ iwadii lori rẹ.