You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Kilódé tí àwọn ọ̀dọ́ Naijiria kò ní ìfẹ́ orílẹ̀èdè wọn?
“Ta lo sọ fun ẹ pe mo le ku fun Naijiria, mi o le ku fun Naijiria laelae.”
Iru awọn ọrọ bayii lo maa n jade lẹnu awọn ọdọ Naijiria laye ode oni, to n tumọ si pe wọn ko nifẹ orilẹede wọn.
Eyii to buru julọ ni pe lẹnu lọlọ yii ni a ri awọn ọdọ kan niluu Kano ti wọn gbe asia orilẹede Russia soke lasiko iwọde ilu le to waye laipẹ yii nibẹ.
Yatọ si eyii, ọpọ ọmọ Naijiria lo n japa kuro nilẹ baba wọn bayii lọna ati ṣeto ọjọ ọla to dara fun ara wọn ati fun awọn ọmọ wọn.
Ẹnikan to jẹ ọmọ ẹgbẹ African Youth Movement, Abdulmajid Sa'ad ni ọrọ naa ti n kọja oju ẹ bayii, ti Naijiria ko ba si ṣọra, yoo padanu ọjọ iwaju rẹ.
Amọ nigba ti ọmọwe Kole Shetiima, to jẹ adari ajọ McArthur Foundation da si ọrọ naa, o ni bo tilẹ jẹ pe lotọ ni awọn ọdọ ko ni ifẹ orilẹede wọn mọ, kii ṣe Naijiria nikan ni irufẹ nnkan bẹẹ ti n waye.
‘Ko si idi kankan fun awọn ọdọ lati fẹran orilẹede Naijiria’
Ọkunrin kan to jẹ adari ninu ajọ Youth Global Vision for Peace in Africa (YGVPA), Comrade Abdulmajid sọ pe ọrọ naa bẹrẹ si n buru bọ lati igba ti Naijria ti pada si ijọba awarawa lọdun 1999.
O ni ijọba ko pese eto ẹkọ to ye kooro ati ohun igbayegbadun fun awọn ọdọ, bẹẹ ni ko mu inu wọn dun.
Gẹgẹ bii ohun to sọ, awọn ọdọ ti wọn n bi lawọn ọdun diẹ sẹyin ko jẹ mudunmudun Naijiria rara.
O fi kun pe ijọba ko ṣe awọn ofin ti yoo mu aye dẹrun fun awọn ọdọ naa.
Ninu ọrọ rẹ, “ti ẹ ba wo o lati nnkan bi ọdun diẹ sẹyin, oniruru iṣoro lo n koju awọn ọdọ.”
Kole Shettima sọ pe Naijiria ti kuna lati ṣe ẹtọ rẹ fun awọn ọdọ.
Awọn mejeji to ba BBC sọrọ sọ pe awọn ọdọ Naijiria ko ri idi kankan ti wọn fi gbọdọ fẹran orilẹede wọn.
Ewu n bẹ loko Longẹ
Ajafẹtọ ọmọniyan naa sọ pe ewu nla lo wa ninu ki ọdọ korira orilẹede rẹ.
Kole ṣalaye siwaju si pe ewu to tobi julọ ninu ki ọdọ korira orilẹede rẹ ni igba ti nnkankan ba ṣẹlẹ to nilo ki irufẹ ọdọ bẹẹ fi ara rẹ jin tabi fi ẹmi ara rẹ rubọ fun orilẹede rẹ, wọ ko ni ṣe bẹẹ.
Abdulmajid Sa'ad ni ojojumọ lawọn ọdọ n fi Naijirila silẹ, bẹẹ ni papakọ ofurufu n kun fun awọn to n japa.
O ni ti irufẹ nnkan bayii ba tẹsiwaju, ọjọ ọla Naijiria yoo fori ṣọpọn.
Bawo ni a sẹ le yi ọkan awọn ọdọ naa pada?
Ọmọwe Kole sọ pe ọna kan gboogi lati yi ọkan awọn ọdọ pada ni lati bẹrẹ si n kọ wọn nipa itan orilẹeede wọn.
Kole sọ pe lootọ ni ọpọ ọdọ kawe daadaa ni Naijiria amọ wọn ko kọ nipa itan orilẹede wọn.
Ọna keji lati yi ọkan awọn ọdọ pada gẹgẹ bii ọrọ Kole ni ki awọn alaṣẹ jẹ ki awọn ọdọ mọ nipa ojuṣe wọ si orilẹede wọn.
Kole ni o ṣe pataki fun gbogbo ọmọ Naijiria lati mọ pe ojuṣe orilẹede wọn ni lati daabo bo wọn lọwọ ewu.
Amọ o fi kun pe ojuṣe araalu si orilẹede rẹ ni lati maa san owo ori rẹ llasio to yẹ, lati kọ orilẹede rẹ ati lati maa tẹle awọn ofin ilana ti ijọba rẹ ba gbe kalẹ.